KWASU: KO SI ẸKUNWO LORI OWO ILEEWE - AWỌN ALAṢẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 9, 2020

KWASU: KO SI ẸKUNWO LORI OWO ILEEWE - AWỌN ALAṢẸ


Awọn alaṣẹ ati adari ile ẹkọ giga fasiti ipinlẹ Kwara, iyẹn Kwara State University to wa lagbegbe Malete ti ke gbajare sita wi pe k'awọn eeyan ma ṣe gba awuyewuye to n lọ kaakiri ori ayelujara wi pe wọn ti fi owo kun owo ileewe t'awọn akẹkọọ n san.
 
Wọn ni ayederu iroyin lasan ti ko l'ẹsẹ nilẹ rara n'iroyin naa.

Gẹgẹ bi atẹjade t'awọn alaṣẹ naa gbe jade laipẹ, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ ni wọn ti sọ pe ijiroro ṣi n lọ lọwọ laaarin awọn alaṣẹ at'awọn aṣoju ẹgbẹ akẹkọọ lati jọ ni asọyepọ nipa owo ileewe naa lojuna lati tubọ mu idagbasoke ba eto-ẹkọ.
 
Atẹjade naa ti Ọgbẹni Mohammed A. Shuaib to jẹ oluforukọsilẹ ileewe naa rọ awọn araalu lati ma ṣe tẹlẹ awuyewuye naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI