AJAGUNGBALẸ NI ILEEṢẸ REVOLUTION PLUS PROPERTY, WỌN N FỌRUKỌ ỌDUNLADE ADEKỌLA LU JIBITI NI – AWỌN ARAALU KẸLẸBẸRI TUN PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 15, 2020

AJAGUNGBALẸ NI ILEEṢẸ REVOLUTION PLUS PROPERTY, WỌN N FỌRUKỌ ỌDUNLADE ADEKỌLA LU JIBITI NI – AWỌN ARAALU KẸLẸBẸRI TUN PARIWO SITA

Lonii l’awọn araalu Kẹlẹbẹri, Ọbada-Oko nitosi Abẹokuta tun ke gbajare s’ijọba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Dapọ Abiọdun lati gba wọn lọwọ ileeṣẹ kan to n ta ilẹ ati ile, iyẹn Revolution Plus Property.

Ohun ti a gbọ ni pe ṣadede ni awọn alaṣẹ ati alakoso ileeṣẹ naa wọ ori ilẹ abule Kẹlẹbẹri, ti wọn si bẹrẹ si i gba ilẹ onilẹ, ti wọn tun n wo ile awọn araalu, ti wọn n kọ ile sori ẹ.

Ni nnkan bi oṣu meloo kan sẹyin la gbe iroyin naa jade sita wi pe awọn ajagungbalẹ yawọ ilu Kẹlẹbẹri, nibi t’awọn agbaagba ilu naa, to fi mọ awọn olugbe ibẹ ti pariwo sita wi pe awọn ajagungbalẹ ko fi wọn lọkan balẹ lọsan-loru.

A gbe e si i yin leti nigba naa wi pe obinrin kan ti wọn pe ni Idowu Fadipẹ, ẹni ti wọn pe ni Iyalaje Ọbada lo wọ ilu Kẹlẹbẹri naa, to si bẹrẹ si i ta ilẹ f’awọn ajagungbalẹ, ti wọn si jẹ ko ye wa pe Idowu Fadipẹ ki i ṣe ọmọ ilu naa, ati pe ko f’ibi kankan tan mọ ilu Kẹlẹbẹri.

Ṣugbọn ni bayii, ohun ti a gbọ ni pe ileeṣẹ Revolution Plus ni wọn ta ilẹ to le ọgbọn ẹẹka fun, lati fi ṣowo ilẹ f’awọn onibara wọn.

Wọn ni ko si oloye tabi baalẹ, tabi ọmọ ilu naa to mọ nipa bi wọn ṣe ta ilẹ fun ileeṣẹ Revolution Plus Property.

Ninu ọrọ t’awọn agbaagba ilu naa b’AWIKONKO sọ ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe ṣe l’awọn alaṣẹ ileeṣẹ ilẹ naa ko awọn tọọgi, to fi mọ awọn agbofinro lati maa fi le awọn araalu at’awọn ọmọ onilẹ danu lori ilẹ wọn.

Bakan naa nibi ifẹhonu han ti wọn tun ṣe l’abule naa lonii ni wọn ti gbe oriṣiriṣi alemode, eyi ti wọn fi n rawọ ẹbẹ s’ijọba ipinlẹ Ogun wi pe ki wọn ba wọn tete wa nnkan ṣe si ọrọ tori pe ẹẹmeji ọtọọtọ l’awọn ti kọ’we ranṣẹ, ṣugbọn ti wọn ko ti i ri esi iwe ti wọn kọ s’ijọba ati ile igbimọ aṣofin.

Wọn ni agba Olu Ọba Ọbada, Ọba Olufẹmi Ṣolaja gan an ko ka ọrọ yii, tori pe ọpọ igba lo ti gbiyanju lati b’awọn alaṣẹ ileeṣẹ yii sọrọ, ṣugbọn ti wọn ni ko sọrọ lori ẹ.

Ọkan lara awọn oloye ilu naa, Ọnọrebu Ṣobọwale Adekunle Alani ninu ọrọ rẹ sọ pe “A ko ta ilẹ fun Revolution Plus Property, lojiji la kan ri i to gbe patako nla sori ilẹ wa nilu Kẹlẹbẹri. Ṣe lo tun ko awọn ṣọja ati ọlọpaa kalẹ lati maa fi le wa danu.

“A ti pariwo titi, a tun ti k’ọwe ẹsun s’ijọba lori ẹ, sibẹ, a ko ti i ri esi kankan gba lati ọdọ ijọba. A ko mọ ẹni to gbe ilẹ wa le Revolution Plus Property lọwọ lati maa ta a nitakuta.

“A n bẹ Gomina Dapọ Abiọdun, Olu Ọbada, Alake ilẹ Ẹgba, a ko mọ bo ṣe d’ori ilẹ wa o, wahala yii ti pọ ju fun wa.”

Bakan naa, iya agba kan t’oun naa jẹ ọkan lara awọn oloye ilu sọ pe “Ole ni Revolution Plus Property, ko ye wa bi wọn ṣe de ori ilẹ wa, a ko ta ilẹ fun wọn rara.

Oloye Mọjeed Ogundimu t’oun naa tun sọrọ sọ pe “Ilẹ awọn baba wa ti a jogun ba lati ọgbọn ọdun le diẹ sẹyin la kan deede ri awọn kan ti wọn pe ni Revolution Plus Property pẹlu awọn ṣọja ati ọlọpaa. Ṣe lo tun gbe katapila wa ti wọn n ge ilẹ bo ṣe wun wọn.

“A ko ta ilẹ fun wọn, a ko le sun labule wa mọ. Agbara oṣelu ni wọn wa n lo le wa lori, wọn si ti láwọn maa fiya jẹ wa pẹlu agbara ti wọn ni. A ko to ẹni to n sun inu ilu mọ bayii.”

Arabinrin Adenikẹ Ṣangodimu ninu ọrọ tiẹ sọ pe “A bẹ ijọba ipinlẹ Ogun ko ba wa da si ọrọ Kẹlẹbẹri, lati ọdun ti a ti n gbe inu ilu yii, pẹlu ifọkanbalẹ ati alaafia ni, ko sẹni to n yọ wa lẹnu, ṣugbọn lojiji ni nnkan bi oṣu mẹrin sẹyin l’awọn Revolution Plus Property de, ti wọn bẹrẹ si i yọ wa lẹnu.

“Awọn ra ilẹ nibi ko le sun, awọn araalu gan ko to ilu de mọ. Gbogbo fẹnsi wa ni wọn ti wo tan, wọn tun wo fẹnsi ile baalẹ wa. Ọba Ọbada ti b’awọn sọrọ, ṣugbọn wọn l’awọn ko ni i gba. Ki ijọba ba wa ba wọn sọrọ lati kuro lori ilẹ wa.”

Ọtun ilu Kẹlẹbẹri, Oloye Lukmọn Ṣangodimu to jẹ “Ẹyin ijọba wa la bẹ lati gba wa lọwọ Idowu Fadipẹ, Nurudeen Alowonle ati Revolution Plus Property. Awa kọ la ta ilẹ fun wọn, ajagungbalẹ ni wọn jẹ lori ilẹ wa.

“A n pe ijọba Dapọ Abiọdun, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, abẹnugọn ile igbimọ aṣofin at’awọn alẹnulọrọ lati gba wa lọwọ ileeṣẹ ajagungbalẹ ti wọn n pe ni Revolution Plus Property.”

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Revolution Plus Property to b’AWIKON sọrọ, ẹni to kọ lati darukọ ara rẹ sọ pe bi awọn baalẹ tabi awọn ọmọ ilu naa ko ba ta ilẹ f’awọn, o l’awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa ko ni bẹrẹ si i ta ilẹ f’awọn onibara wọn nibẹ.

Ẹni naa sọ pe ko si anfaani fun wa lati ba alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ naa sọrọ, ati pe bi a ba fẹ ri alaṣẹ, afi ka kọ iwe si ileeṣẹ wọn to wa ni Ita-Ẹkọ nilu Abẹokuta.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI