Ẹ̀WỌ̀N GBÉRE: ÀWỌN ỌMỌ ÌJỌ SỌTITOBIRẸ L'AWỌN KÒ NÍ I GBÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, October 14, 2020

Ẹ̀WỌ̀N GBÉRE: ÀWỌN ỌMỌ ÌJỌ SỌTITOBIRẸ L'AWỌN KÒ NÍ I GBÀ


Àwọn ọmọ ṣọọṣi Sọtitobirẹ Miracle Centre to wá n'ilu Akurẹ, ìpínlẹ̀ Ondo tí làwọn kò ní í gba idajọ ẹ̀wọ̀n gbere tí wọn dá fún oludasilẹ àwọn rárá, dípò bẹ́ẹ̀, wọn làwọn ń lọ sile ẹjọ́ agba láti pé ẹjọ́ kotẹmilọrun. 

L'ọjọ Iṣẹgun-Tuside ọ̀sẹ̀ to kọjá ní Onidajọ Oluṣẹgun Oduṣọla tí ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Òndó ju oludasilẹ ṣọọṣi náà, Wòlíì Babatunde Alfa pẹ̀lú àwọn márùn-ún mi ín sí ẹ̀wọ̀n gbere lórí esun ijinigbe àti ipaniyan. 

Ọkan lára àwọn ọmọ ṣọọṣi náà bá oniroyin sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìdájọ́ náà sọ pé ó kú díẹ̀ kaato, àti pé àwọn kò lè làjú silẹ káwọn alaiṣẹ máa jìyà aimọdi. 

Ẹni náà ni ọdún kẹfà rèé tòun ti ń jọsin nínú ìjọ ṣọọṣi Sọtitobirẹ, tí Ọlọ́run sì ń lò Wòlíì Babatunde Alfa láti dáhùn àwọn ẹ̀bẹ̀ àdúrà òun. Ó lòun kò ti í ṣalabapade oògùn abẹnugọngọ lọ́wọ́ ẹ tàbí kó sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó mú Ọlọ́run miran mọ Jésù. 

"Ó yà wá lẹ́nu pé wọn lé ju Wòlíì tí kò mọ nnkankan sẹwọn gbere. Wọn kò ti í rí ọmọ tí a ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ yìí, kí ni yóò wá ṣẹlẹ̀ bí wọn ba ri ọmọ náà ni ọla? 

"A fi ka pé ẹjọ́ kotẹmilọrun, a sì fẹ́ káwọn ọmọ Nàìjíríà olórí pípé dìde iranlọwọ fún Wòlíì Babatunde". 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI