Ẹ̀GBỌ́N ÀTI ÀBÚRÒ DERO ATIMỌLE, ỌMỌ ỌDÚN MẸ́RÌNDÍNLÓGÚN NI WỌN FIPÁ BÁ LÁṢẸPỌ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 16, 2020

Ẹ̀GBỌ́N ÀTI ÀBÚRÒ DERO ATIMỌLE, ỌMỌ ỌDÚN MẸ́RÌNDÍNLÓGÚN NI WỌN FIPÁ BÁ LÁṢẸPỌ̀


Atimọle ọlọpaa làwọn ọmọ ìyá kan náà méjì wá bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí lórí ẹ̀sùn wí pé wọn fipá bá ọmọdé bìnrin ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún kan laṣẹpọ.

Ọjọ́rú-Wẹside to kọjá yìí là gbọ ọwọ tẹ àwọn ọmọ iya méjì yìí pẹ̀lú ọ̀rẹ́ wọn. Abúlé kan tí wọn pé ní Pátá Abiọdun ni wọn ti fìpa bá ọmọ náà laṣẹpọ.

Oluwaṣeun Damilohun, ọmọ ogún ọdún; Oriyọmi Damilohun, ọmọ ọdún mọkandinlogun àti Oluwaṣẹgun Idowu, ọmọ ọdún méjìdínlógún làwọn mẹtẹẹta tí ọwọ tẹ. 

AWIKONKO gbọ pé ibi tí ọmọ náà tí ń wẹ lọ́wọ́ ni baluwẹ ni wọn ti lọ bá a, tí wọn sì tún yà fọnran rẹ sórí fóònù.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI