GBAJUMỌ AKỌROYIN GBÉ AYẸYẸ ỌJỌ́ ÌBÍ OGÓJÌ ỌDÚN WỌ ṢỌỌṢI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 18, 2020

GBAJUMỌ AKỌROYIN GBÉ AYẸYẸ ỌJỌ́ ÌBÍ OGÓJÌ ỌDÚN WỌ ṢỌỌṢI


Gbogbo àgbáyé ni wọn ń bá Arábìnrin Modupẹọla Ogundipẹ Ṣobukọnla ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí ogójì ọdún rẹ títí di àsìkò tí a parí ìròyìn yìí.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òní ni ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ, ṣùgbọ́n lati ijẹta, ọjọ́ Ẹti-Furaide to kọjá yìí làwọn olólùfẹ́ obìnrin náà tí ń kii kú oriire fún ayẹyẹ yìí. 


Òṣìṣẹ́ ileeṣẹ rédíò ìjọba àpapọ̀ tó wà n'ilu Abẹ́òkúta, ìyẹn Paramount FM, ẹ̀ka ileeṣẹ Rédíò Nàìjíríà ni Dúpẹ́ Ṣobukọnla. 

Dúpẹ́ ni alága ẹgbẹ́ àwọn akọroyin-l'obinrin, ìyẹn NAWOJ nipinlẹ Ogun. 

Lónìí ní obìnrin náà gbé ayẹyẹ ọjọ́ ìbí náà wọ inú ṣọọṣi láti fi imọriri rẹ hàn sí Ẹlẹda rẹ, tó sì ń dúpẹ́ fún oore tí kò wọ́pọ̀ náà. 

AWIKONKO náà ń fi àsìkò yìí bá Arábìnrin Modupẹọla Ogundipẹ Ṣobukọnla yọ fún àánú ńlá tó rí gbà láti bẹ̀rẹ̀ akasọ kẹrin ni ìgbésí ayé rẹ. 

Àdúrà wa ni pe wá a ṣe pupọ ọdún láyé nínú àlàáfíà àti ìdùnnú, wá a sì jẹun ọmọ kalẹ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI