#ENDSARS: ỌWỌ́ TẸ LAWAL TO JI FÓÒNÙ NÍBI ÌFẸ̀HÓNÚHÀN NI LEKKI, NI WỌN BÁ DÁNÁ ÌYÀ FUN UN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 18, 2020

#ENDSARS: ỌWỌ́ TẸ LAWAL TO JI FÓÒNÙ NÍBI ÌFẸ̀HÓNÚHÀN NI LEKKI, NI WỌN BÁ DÁNÁ ÌYÀ FUN UN


Kí i ṣe ahesọ mọ wí pé eepo tí dá mọ àlìkámà àwọn tó ń fẹhonuhan lórí ifiyajẹni àwọn ọlọpaa SARS, nítorí bí wọ́n ṣe làwọn tọọgi tí ń sá sábẹ́ asia #ENDSARS tó ń lọ lọ́wọ́.

Bi gendekunrin ọmọ ọdún marundinlọgbọn tí ẹ wo yìí bá fi bọ nínú wàhálà tó fà si ara rẹ lẹsẹ yìí, tó bá tún gbìyànjú láti jalè, afaimọ ni kò bá jẹ pe ibi yóò gbà kúrò láyé nìyẹn. 

Gendekunrin yìí, Yusuf Lawal ni wọ́n pè orúkọ rẹ, agbegbe Ojuẹlẹgba n'ilu Èkó lo ń gbé, kò sì ní iṣẹ mi ín kọjá olè jíjà àti gbajuẹ lọ. 

Ọjọ́ Satide-Abamẹta àná lọ́wọ́ tẹ Lawal ni Toll-Gate Lẹkki, níbi táwọn èèyàn ti ń fẹhonuhan lórí ENDSARS àti ENDSWAT.

Fóònù olówó iyebíye là gbọ pé Lawal jigbe, níbi ifẹhonuhan náà, tí ọwọ palaba ẹ sì ti segi. 

Lójú ẹsẹ̀ tí àṣírí Lawal tí tú pé ó jí fóònù gbé lo tí fún lára àwọn tí wọn jọ ń jalè, ṣùgbọ́n tí yẹn raaye júbà ehoro. Nibẹ sì ni wọn ti ko ìyà ayérayé fún un, tí kò sì lè gbàgbé lailai. 

Àwọn ẹlẹyinju àánú ni wọn ba a bẹbẹ pé kí wọn fà á lé àwọn ọlọpaa lọ́wọ́ láti ṣe ìwádìí ẹ, tí wọn sì fà á lé àwọn ọlọpaa agbegbe Marọkọ lọ́wọ́, níbi tó ti ń ṣàlàyé bo ṣe máa jalè fún wọn. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI