MC OLUỌMỌ KÒ RA ILÉ FÚN MI Ò - ÒGO MUṢHIN PARIWO SÍTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 18, 2020

MC OLUỌMỌ KÒ RA ILÉ FÚN MI Ò - ÒGO MUṢHIN PARIWO SÍTA


Ọkàn lára àwọn gbajumọ oṣerebinrin nnì, Ọlayinka Sọlomọn táwọn olólùfẹ́ rẹ mọ sì Ògo Muṣhin tí pariwo síta wí pé kí í ṣe alaga ẹgbẹ́ onimọto nipinlẹ Èkó, MC Oluọmọ kọ lo ra ilé f'oun. 

Ọlayinka sọ pé ilé náà kì í ṣe dúkìá tòun ra, bí kò ṣe pé ṣe loun ra ilẹ̀ tòun sì kọ ilé sórí ẹ pẹ̀lú owó ọwọ ara òun. 

Ṣe ni awuyewuye jáde síta laipẹ yìí nígbà tí Ọlayinka ń ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí ẹ pẹ̀lú mọto tuntun, nibẹ làwọn èèyàn ti ń sọ pé kò sẹni méjì tó ra ilé náà fún un bí kò ṣe MC Oluọmọ. 

Ó ní ilé náà kì í ṣe ilé àkọ́kọ́ tòun yóò kọ, àti pé koun too kúrò lábẹ́ bàbà òun loun tí di ẹni tó ń ní ilé lórí nítorí pé iṣẹ ilé kíkọ ni bàbá òun yàn láàyò. 

Síwájú sí í lo sọ pé ilé náà ní yóò jẹ ẹlẹẹkẹta tòun yóò kọ, àti pé àwọn ayalegbe tí yà gbogbo rẹ tán lo jẹ́ koun ronúati kọ ilé mi ín. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI