IJỌBA IPINLẸ OGUN KEDE IGBALE-GBATA LỌJỌ SATIDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 29, 2020

IJỌBA IPINLẸ OGUN KEDE IGBALE-GBATA LỌJỌ SATIDE


Ijọba ipinlẹ Ogun ti kede wi pe ọjọ Abamẹta ti i ṣe Satide to n bọ yii ni igbale-gbata yoo waye kaakiri ipinlẹ naa, to si n rọ gbogbo awọn araalu wi pe ki wọn tẹle ilana ijọba.

'Imọtoto lo le ṣẹgun arun gbogbo' lorin ti ijọba n kọ f'aọn araalu bayii, to si n ni ki wọn gbiyanju lati tun awọn ayika ati agbegbe wọn ṣe, lojuna lati le dẹkun ajakalẹ arun.

O ni laaarin aago meje aarọ si aago mẹwaa aarọn ni eto imọtoto naa yoo fi waye kaakiri gbogbo ioinlẹ Ogun ati agbegbe rẹ lojọ Abamẹta to gbéyin oṣu kẹwaa, iyẹn ọjọ kọkanlelọgbọn.

Kọmiṣanna fun eto ayika, Ọnọrebu Abiọdun Abudu-Balogun lo kede iroyin yii sita lonii, to si ni k'awọn araalu ri i daju pe bi wọn ṣe gba ilẹ ayika wọn naa ni wọn n fọ awọn gọta wọn mọ tonitoni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI