LẸ́YÌN Ọ̀SẸ̀ MẸ́TA, ÀJỌ NEMA FẸẸ ṢE IRANLỌWỌ FÁWỌN ÈÈYÀN ÌPÍNLẸ̀ KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, October 13, 2020

LẸ́YÌN Ọ̀SẸ̀ MẸ́TA, ÀJỌ NEMA FẸẸ ṢE IRANLỌWỌ FÁWỌN ÈÈYÀN ÌPÍNLẸ̀ KWARA


Lẹ́yìn ọsẹ kẹta tí Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq ṣe abẹwo sì ileeṣẹ àjọ tó ń rí sì ìṣẹ̀lẹ̀ pajawiri lórílẹ̀-èdè yìí, ìyẹn National Emergency Management Agency, NEMA lórí omiyale to ṣe ijamba fáwọn aráàlú, ajọ náà tí sọ pé àsìkò tí tó láti ṣe iranlọwọ fún wọn. 

Òní tí í ṣe Tuside làwọn tí wọn kagbako nínú ìṣòro omiyale, agbára yà ṣọọbu náà yóò gbà àwọn nǹkan iranlọwọ tí ìjọba nípasẹ̀ àjọ NEMA. 

Gẹ́gẹ́ bí atẹjade tí akọ̀wé gómìnà lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Rafiu Ajakaye fi ranṣẹ sì AWIKONKO, ó ní oṣù mẹta sẹ́yìn ni Gomina lọ bá Alakoso àgbà fún àjọ NEMA, AVM Muhammadu Muhammed ṣe ìpàdé, tó sì ṣàlàyé lẹkunrẹrẹ ohun táwọn èèyàn pàdánù, nibẹ lo ni wọn ti sọ pé àwọn yóò ṣe iranlọwọ fún wọn. 

Látìgbà náà là gbọ pé Gómìnà AbdulRazaq pẹ̀lú ọkàn lára àwọn aṣofin àgbà orílẹ̀ èdè yìí tó jẹ́ ọmọ Ìpínlẹ̀ náà, Sẹnetọ Ibrahim Oloriẹgbẹ tí ń gbé igbesẹ láti tètè rí iranlọwọ náà gbà fáwọn aráàlú. 

Àwọn èèyàn ti wọn pàdé àgbákò yìí làwọn agbègbè bí í Ilọrin West, Ilọrin East, Ilọrin South, Asa ati Ifẹlodun ni wọn yóò jẹ àǹfààní náà, gẹ́gẹ́ atẹjade tí adari fidihẹ àjọ náà, Ọmọwe Onimọdẹ Bándélé fi ranṣẹ sì ìjọba Kwara. 
 
O ni minisita tó ń rí sọ̀rọ̀ àkóso ìṣẹ̀lẹ̀ pajawiri, Hajia Sadiya Umar Farouk ni yóò wá pín àwọn ẹ̀bùn náà fáwọn aráàlú lónìí. 

Lára nnkan ti wọn si fẹẹ fún àwọn èèyàn ni: 3,844 Bags of Rice (12.5kg); 3,844 Bags of Beans (25kg); 3,844 Bags of Maize (12.5kg); 384 Kegs of Vegetable Oil; 641 Cartons of Seasoning;  320 Cartons of Tinned Tomatoes;  192 Bags of Salt;  7,000 Pieces of Mattresses ati  7,000 Pieces of Wax Prints. 

Àwọn yòókù ni: 7,000 Pieces of Mosquito Nets; 7,000 Pieces of Nylon Mats; 7,000 Pieces of Blankets; 4,500 Pieces of Ceiling Boards; 4,500 Bags of Cement; 4,500 Bundles of Roofing Sheets; 1,500 Packets of Zinc Nails; ati 500 Bags of 3’ Nails.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI