ẸNIỌLA BADMUS GBÉ FỌ́TÒ ÌDAJÌ ARA RẸ̀ SÍTA, LÀWỌN ÈÈYÀN BÁ NÍ ỌJÀ TÍ TÁN L'ORI IGBA Ẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 30, 2020

ẸNIỌLA BADMUS GBÉ FỌ́TÒ ÌDAJÌ ARA RẸ̀ SÍTA, LÀWỌN ÈÈYÀN BÁ NÍ ỌJÀ TÍ TÁN L'ORI IGBA Ẹ


Gbajugbaja oṣerebinrin ti a mọ si Ẹniọla Badmus lo tun ti da ori ikanni ayelujara ru bayii, nitori pe ọrọ rẹ ni gbogbo aye, paapaa awọn ololufẹ rẹ n sọ bayii.
 
Fọto idaji ihoho ara rẹ kan ni Ẹniọla gbe sita lori ikanni ayelujara ti Instagram, nibi to ti wọ aṣọ ti wọn ma fi n wẹ ninu odo igbalode, iyẹn Bikini.
 
Bo ṣe gbe fọto naa sita l'awọn kan ti n fi ọrọ idunnu ranṣẹ si i pe mama ṣi duro sibẹ, t'awọn kan n sọ pe o gbẹnu tan, ati oriṣiriṣi bẹẹ lo.
 
B'awọn kan ṣe n sọrọ gidi si Ẹniọla, bẹẹ l'awọn kan n sọ pe ọja ti tọ lori igba rẹ, pẹlu bi ọmu ẹ ṣe jo wa silẹ bi tẹni to ṣẹṣẹ pari fifun ọmọ lọmu.
 
Ọrọ yii ni wọn lo o bi Ẹniọla ninu to fi da lara awọn to n sọrọ buruku naa si i pe idahun wa nilẹ fun wọn, to si ni bi ọmu mama wọn ṣe ja walẹ naa ni t'oun naa ja walẹ.
 
Ṣaaju asiko ni Ẹniọla funra rẹ ti kọ ọrọ ikilọ kan sabẹ fọto rẹ yii pe k'awọn to jẹ pe irikuri loju wọn maa n ri ni gbogbo igba dakẹ ẹnu wọn.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI