DAVID TI WỌ́N LO JI ỌMỌ ỌDUN MEJI GBE L'ỌTA TI FOJU BA ILE-ẸJỌ O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 10, 2020

DAVID TI WỌ́N LO JI ỌMỌ ỌDUN MEJI GBE L'ỌTA TI FOJU BA ILE-ẸJỌ O


Ọjọ Ajẹ-Mọnde ana ni baale ile kan ti wọn f'ẹsun ijinigbe kan ti f'oju ba ile ẹjọ majisireeti to wa ni Ọta, ipinlẹ Ogun. Ọmọdekunrin, ọmọ ọdun meji la gbọ pe o jigbe.
 
Adetoro David lorukọ ẹni ọdun mẹrinlelogoji ni wọn pe ẹ. Ọmọ ọdun meji to jẹ ti Ọgbẹni Yẹmi Oluwọle ati iyawo rẹ ni wọn sọ pe David jigbe lagbegbe Oju-Ore to wa ni Ọta

Ẹsun ti wọn fi kan David ni wọn lo tako iwe ofin ọdaran t'ipinlẹ Ogun t'ọdun 2006, to si ni ijiya ninu.
 
Nigba to n sọrọ, Onidajọ naa, O. L Ọkẹ  f'oju aanu wo David, to si ni ki wọn gba beeli ẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna igba (200,000) naira pẹlu oniduro meji ti wọn ko jinna si ayika ile-ẹjọ naa, ati pe awọn oniduro naa gbọdọ jẹ awọn to n san owo ori wọn deedee fun ijọba ipinlẹ Ogun.
 
O wa sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kọkandinlogun oṣu yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI