Ẹ PÀDÉ YINKA ỌLAJIDE, ÒGO ÌPÍNLẸ̀ OGUN TUNTUN NÍBI ERÉ SISA LORILẸ-EDE NÀÌJÍRÍÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 25, 2020

Ẹ PÀDÉ YINKA ỌLAJIDE, ÒGO ÌPÍNLẸ̀ OGUN TUNTUN NÍBI ERÉ SISA LORILẸ-EDE NÀÌJÍRÍÀ


Bí wọn ba n sọ pé ta ló mọ ère sá julọ n'ipinlẹ Ogun lásìkò yìí, pàápàá láàárin àwọn ọdọbinrin, ipò akọkọ ni Ọlayinka Àjàyí Ọlajide wá, ẹni tó ti gbegba oroke lọpọlọpọ ìgbà nibi ère sisa. 

Ọmọ bíbí ìlú Ifọ n'ijọba ìbílẹ̀ Ifọ, ìpínlẹ̀ Ogun ni Ọlayinka Ọlajide tọpọ àwọn èèyàn mọ sí AJ-GOLD. 

Ó ti sá ère ọlọọkan oni 100m àti 200m, tó sì ti borí làwọn ìdíje loriṣiriṣi. 

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ, AJ-GOLD ni yóò ṣojú ipinlẹ Ogun nínú ìdíje ère sisa tí 100m àti 200m orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ìyẹn National Sports Festival tó yẹ kó wáyé n'ilu Benin, ìpínlẹ̀ Edo lọ́jọ́ kẹta sí ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejìlá ọdún yìí, ṣùgbọ́n tí wọn tí sún síwájú di ọdún 2021 tó ń bọ̀. 

Ilé ẹ̀kọ́ gíga gbogboniṣe tí Moshood Abiọla, MAPOLY ni AJ-GOLD tí parí ipele àkọ́kọ́ gíga ẹ̀kọ́ rẹ, ìyẹn ND lẹka imọ ẹ̀kọ́ Science Laboratory Technology, to sì jẹ pe fasiti àgbẹ̀ àti ọgbin, ìyẹn Federal University of Agriculture, Abẹ́òkúta lo tí ń kẹ́kọ̀ọ́ imọ Chemistry lọ́wọ́lọ́wọ́, ipele kẹta tí a mọ sí 300l ló wà níbẹ̀. 


Ògo ipinlẹ Ogun ni Ọlayinka Àjàyí Ọlajide lásìkò yìí, tó sì ń fi tọkàntọkàn pelu ìtara jà láti rí í pé orúkọ ipinlẹ náà ń gbà iyì káàkiri àgbáyé. 

Ẹ bá wà fi àdúrà ranṣẹ sì í. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI