O MA ṢE O! Ẹ WO IYAALE ILE TO FẸẸ TA ỌMỌ OṢU MẸTA DANU NITORI EBI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 25, 2020

O MA ṢE O! Ẹ WO IYAALE ILE TO FẸẸ TA ỌMỌ OṢU MẸTA DANU NITORI EBI


Iyaale ile ẹni ọdun mọkanlelogun yii lọwọ ọlọpaa ipinlẹ Anambra ti tẹ lasiko to n gbiyanju lati ta ọmọ rẹ, ọmọ oṣu mẹta danu nitori ebi ati iya to lo n ba oun finra.
 
Obinrin naa, Emilia Sunday, ọmọ bibi ipinlẹ Ebonyi naa sọ pe ẹgbẹrun lọna aadọjọ (150,000) naira pere loun fẹẹ ta ọmọ naa nitori bo ṣe sọ pe oun ko ri ounjẹ gidi jẹ, eyi toun yoo maa fi fun ọmọ naa ni ọmu deede.
 
Awọn kan ti wọn sọ pe ọrọ naa ta si leti lasiko ti wọn ni Emilia n ba ẹnikan sọrọ lati ta ọmọ naa la gbọ pe wọn ta awọn ọlọpaa lolobo, ko to di pe wọn lọ sibi to ti fẹẹ ta ọmọ naa danu, iyẹn lọjọ kẹrinlelogun ti i ṣe Tusidee ana.
 
Nnkan bi aago mẹfa irọlẹ la gbọ pe ọwọ tẹ Emilia ni abule kan ti wọn pe ni Ire, Ojoto. Awọn ọlọpaa ẹkun Ojoto to wa n'ipinlẹ naa la gbọ pe wọn ṣiṣẹ yii.
 
Bi ẹ ṣe n ka iroyii ni iwadii ṣi n lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI