TIṢA LU AKẸKỌỌ RẸ PA L'EKOO, LO BA NA PAPA BORA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 30, 2020

TIṢA LU AKẸKỌỌ RẸ PA L'EKOO, LO BA NA PAPA BORA


Adura ti ọpọ awọn eeyan maa n gba pe 'Ọlọrun ko ni i jẹ k'awọn ọta gba ọmọ wa na pa' ko gba rara fun ọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Emmanuel, olukọ ileẹkọ kan nilu Eko ti wọn lo o lu ọkan lara awọn akẹkọọ rẹ, Boluwatifẹ Omelaja pa.
 
Ile ẹkọ Elihans College to wa ni Isawọ nilu Ikorodu, Eko la gbọ pe iṣẹlẹ naa ti waye l'Ọjọbọ ti i ṣe Tọsidee ọsẹ to kọja yii nigba ti wọn sọ pe Emmanuel t'ọpọ awọn akẹkọọ n pe ni Mr Emma beere ibeere ninu ẹkọ iṣiro, iyẹn mathematics lọwọ Boluwatifẹ, eyi ti wọn ni ko le dahun daadaa, to si ṣe bẹẹ luu pa.
 
Iṣẹlẹ yii ni wọn ni ko ṣẹyin aburo Boluwatifẹ ti wọn sọ pe ileewe kan naa ni wọn jọ n lọ.
 
Bi Boluwatifẹ ṣe ku la gbọ pe wọn ti ronu irọ ti wọn yoo pa, to si mu ki wọn gbe oku ẹ lọ sile f'awọn obi ẹ lati sọ fun wọn pe ṣe lo yọ ṣubu, to si ku loju ẹsẹ.
 
AWIKONKO gbọ pe latigba naa ni wọn ti sọ fun Emmanuel pe ko lọ farapamọ sibi ti wọn ko ti ni i ri i bi aṣiri ba pada tu sita, ti ko si sẹni to mọ ibi to wa titi d'asiko yii.
 
Loju ẹsẹ la gbọ pe wọn ti lọ sin Boluwatifẹ nilana musulumi, ṣugbọn ṣe ni ọrọ yi pada nigba ti wọn sọ pe aburo Boluwatifẹ dele, to si ṣalaye bi ọrọ naa ṣe jẹ f'awọn obi ẹ wi pe tiṣa lo luu pa lasiko ti ko le dahun ibeere daadaa.
 
Agbẹnusọ ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ẹkọ nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Kayọde Abayọmi sọ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI