O PARI O! AWỌN TỌỌGI GBA IBỌN LỌWỌ ṢỌJA, WỌN KỌJU IJA S'AWỌN KỌSITỌỌMU L'ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 30, 2020

O PARI O! AWỌN TỌỌGI GBA IBỌN LỌWỌ ṢỌJA, WỌN KỌJU IJA S'AWỌN KỌSITỌỌMU L'ABẸOKUTA


Ṣe lọrọ di boolọ o yago lọna l'ọsẹ to kọja yii nigba ti wọn l'awọn tọọgi kọju ija s'awọn oṣiṣẹ aṣọbode ti i ṣe kọsitọọmu lagbegbe Lafẹnwa to wa nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
 
Ko si nnkan meji ti wọn lo da wahala silẹ bi ko ṣe ti irẹsi ti wọn l'awọn onifayawọ ko wọle lọjọ Fraide to kọja yii, eyi ti wọn l'awọn kọsitọọmu lọ dena de wọn, ti wọn si gba a lọwọ wọn.
 
Pẹlu ibinu la gbọ pe awọn tọọgi fi dena de awọn kọsitọọmu yii, ti wọn si koju ija si wọn, tọrọ naa si di ija igboro. 
 
Lara awọn to f'iṣẹlẹ naa to wa leti jẹ ko ye wa pe ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn pe ni Abacha lo lewaju awọn tọọgi lọjọ naa lati kọju ija s'awọn kọsitọọmu.
 
Wọn jẹ ko ye wa pe ọfiisi l'awọn kọsitọọmu gbe tirela irẹsi naa lọ ko to di pe awọn tọọgi yii ya lọ ba wọn, ti wọn si l'awọn ọlọpaa to tẹlẹ wọn lọ naa fi ara gba apa.
 
N'igba ti wọn ri i pe agbaraawọn ọlọpaa ko fẹ ka wahala naa ni wọn lo o jẹ ki wọn ranṣẹ pe awọn ṣọja fun iranlọwọ. Wọn ni b'awọn ṣọja naa ṣe debẹ l'awọn tọọgi yii ti gba ibọn lọwọ ọkan lara wọn, ti wọn si gbe ibọn naa salọ.
 
Pẹlu ibinu ni wọn l'awọn ṣọja naa fi le awọn tọọgi yii danu, ti wọn si di gbogbo ọna to wọ ibi t'awọn kọsitọọmu naa wa.
 
Agbẹnusọ awọn ọlọpaa, Abimbọla Oyeyẹmi fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, o si fi ye wa pe wọn ti gba ibọn naa pada lọwọ awọn tọọgi yii, ati pe iwadii ṣi n lọwọ, paapaa lati rọwọ to olori wọn ti wọn pe ni Abacha.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI