MO TI ṢETAN LATI GBA IJỌBA LỌWỌ BUHARI L'ỌDUN 2023 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 3, 2020

MO TI ṢETAN LATI GBA IJỌBA LỌWỌ BUHARI L'ỌDUN 2023


Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi Citadel Global Church, Pasitọ Tunde Bakare ti sọ pe oun ti n gbaradi fun idibo Aarẹ ọdun 2023 to n bọ lorilẹ-ede yii.
 
Pasitọ Tunde Bakare ni gẹgẹ bi ojulowo ọmọ Naijiria, ipo to ba wu oun loun lẹtọ si lati gbe apoti ẹ, ati pe gbogbo ipinu oun bayii ni lati di Aarẹ Naijiria l'ọdun 2023.
 
Ori tẹlifiṣan Arise ni Bakare ti sọrọ yii nibi ifọrọwerọ to ṣe pẹlu awọn oṣiṣẹ ibẹ.
 
O ni oun ko le fọwọ lẹran lati sọ pe koun maa wo bi nnkan ṣe n lọ mọ, ati pe nipasẹ oore ọfẹ Ọlọrun, oun gbọdọ da si ọrọ Naijiria, nitori pe ṣe lo dabi ọrọ iku ati iye.
 
Siwaju si i lo tun sọ pe oun naa ṣetan lati gbaruku ti eeyan gidi, ati pe oun naa n f'oju sọna lati fa ara oun kalẹ, iyẹn b'awọn ọmọ Naijiria ba le gbaruku ti oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI