GBEGEDE GBINA! PRIMATE AYỌDELE SỌ ASỌTẸLẸ IBẸRU NIPA ỌDUN 2021 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 28, 2020

GBEGEDE GBINA! PRIMATE AYỌDELE SỌ ASỌTẸLẸ IBẸRU NIPA ỌDUN 2021


Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI kaakiri agbaye, Wolii (Primate) Elijah Ayọdele ti sọ pe gbegede yoo gbina lọdun 2021, ti nnkan yoo si tun daru mọ awọn alagbara orilẹ-ede Naijiria loju, ati pe ayafi bi wọn ba gbadura.
 
Bakan naa lo sọ pe bi awọn alaṣẹ ko ba tẹra mọ adura, oku yoo sun ninu ile agbara orilẹ-ede yii, iyẹn Aso-Rock nilu Abuja. Bẹẹ lo tun sọ pe ọga awọn alakatakiti Boko Haram, iyẹn Abubakar Shekau yoo ko si pampẹ. 
 
Ohun to ba pupọ awọn eeyan lẹru ni bo ṣe jẹ pe asọtẹlẹ to le ni igba (200) ni Wolii Ayọdele ju kalẹ, to si ni atunto ati adura nikan lo le ṣẹgun wọn.
 
Wolii naa, to maa n sọ asọtẹlẹ lọdọọdun nipa awọn isẹlẹ ti yoo waye ninu ọdun tuntun tun ṣalaye pe awọn agbegbọn yoo tubọ kọlu ilu Abuja lọdun 2021. 
 
Bakan naa lo tun ni aawọ to maa n waye laarin awọn agbẹ ati darandaran yoo tubọ pọ si ninu ọdun 2021 ati siwaju si i, jakejado Naijiria. 
 
Ko tan sibẹ, Wolii Ayọdele ni laipẹ-laijinna ni ọwọ palaba aṣaaju ikọ Boko Haram, Abubakar Shekau yoo segi, ti ina yoo si dilẹ lẹyin asunsunjẹ rẹ.

Nigba to n sọrọ lori epo rọbi, ojisẹ Ọlọrun naa sọ asọtẹlẹ pe awọn ileepo ifọpo rọbi to jẹ ti ijọba yoo tubọ dojude, ti wọn yoo si di akurẹtẹ amọ ileepo aladani ti Dangote kọ yoo gbinnaya.

Bakan naa ni Ayodele sasọtẹlẹ pe o seese ki aarẹ to wa lori aleefa ati ọkan lara awọn aarẹ to ti jẹ tẹlẹ jade laye, ti omiran yoo si fi asọ penpe roko ọba.

O tẹsiwaju pe awọn gende agbebọn yoo kọlu awọn sọọsi pupọ ninu ọdun 2021, ti wọn yoo si tun maa ji awọn asaaju ijọ gbe lọ pẹlu.

Bakan naa lo ni ọpọ awọn oloselu ni yoo dero ọrun lairotẹlẹ nitori ikọlu oselu lọdun 2021.

"Ikọlu nla yoo waye lati ọdọ awọn Darandaran si awọn agbẹ ni ẹkun ariwa ati ila oorun Naijiria, ti Ọlọrun si fi han mi pe ọpọ awọn darandaran naa ni wsn n lo fun awọn idi kan, ti asiri rẹ ko ni pẹ tu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI