AKEREDOLU WỌ GAU NI INDIA, JIBITI OWO NLA LO LU WỌN NIBẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, January 8, 2021

AKEREDOLU WỌ GAU NI INDIA, JIBITI OWO NLA LO LU WỌN NIBẸ


Joseph Akeredolu, ẹni ọdun mejidinlaadọta lo ti wọ gau lorilẹ-ede India bi ẹ ṣe n ka iroyin yii. Jibiti owo nla kan la gbọ pe Akeredolu lu ẹnikan ti wọn lo wa lati South Mumbai.
 
Rs 1.16 crore to jẹ $217,000 la gbọ pe Akeredolu lu jibiti ẹ. Orukọ olorukọ la gbọ pe Akeredolu fi n lu awọn eeyan ni jibiti lori ikanni ayelujara pẹlu ẹtanjẹ lati maa fi ẹbun ranṣẹ si wọn.
 
AWIKONKO gbọ pe ṣe ni Akeredolu lọ ba ẹni naa ti wọn pe ni Diamon Broker to n gbe ni Girgaon, to si ni ọfiisi ni Bharat Diamond Bourse ni BKC. Ori ikanni ayelujara ti Instagram la gbọ pe Akeredolu ti ba ẹni naa duna-dura lọjọ kẹwaa oṣu kẹwaa ọdun to kọja.
 
Orukọ obinriin kan, Alex Zendra la gbọ pe Akeredolu fi n lu jibiti, to si loun ni Balogun ọkọ ori omi kan ni UK, ti wọn si bẹrẹ si i sọrọ. Ko pẹ la gbọ pe iduna-dura wọn wọ, ti wọn si ni Akeredolu lo orukọ Zendra naa lati fi ẹni naa ṣe ọkọ.
 
Latigba naa lo ti bẹrẹ si i gba owo lọwọ ẹni naa, ko to di pe aṣiri tu sita, t'ọwọ ọlọpaa si ti tẹ ẹ bayii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI