Ẹ WO OJU ỌLỌDẸ TO JI APOTI OWO ỌRẸ ATI IDAMẸWAA ṢỌỌṢI GBE L'OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, January 8, 2021

Ẹ WO OJU ỌLỌDẸ TO JI APOTI OWO ỌRẸ ATI IDAMẸWAA ṢỌỌṢI GBE L'OGUN


Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, ko daju pe Mela Samaila ti wọn f'ẹsun kan pe o ji apoti owo ọrẹ ati idamẹwaa ṣọọṣi kan ti wọn pe ni Grace Nations Church to wa ni Ojodu, ipinlẹ Ogun yoo bọ ninu wahala afọwọfa rẹ.
 
Ṣọọṣi naa ti wọn tun n pe ni Liberation City la gbọ pe Samaila ti n ṣiṣẹ ọlọdẹ tẹlẹ ri, ko to di pe wọn le e danu lẹyin awọn iwa buruku kan ti wọn lo hu nibẹ.
 
Nnkan bi aago mẹrin oru lasiko t'awọn eeyan ti sun la gbọ pe Samaila fo fẹnsi wọnu ọgba ṣọọṣi naa, to si gbe apoti owo ọrẹ ati idamẹwaa ti wọn lo kun fun ọpọlọpọ owo salọ.
 
Awọn ti wọn n ṣiṣẹ gẹgẹ bi ọlọdẹ ni ṣọọṣi naa ko to di pe wọn le Samaila danu la gbọ pe wọn fura si i lẹyin ti wọn lọ fi to awọn ọlọpaa leti, ta a si gbọ pe wọn ọwọ ẹ ni wọn ti pada ba apoti owo ọrẹ naa.
 
Ko sọrọ meji ti wọn lo jade lẹnu Samaila ju 'o pari' lọ n'igba t'aṣiri ẹ tu sita.
 
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Ajogun ti paṣẹ pe ki wọn lọ f'oju Samaila ba ile ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI