AYẸYẸ ỌDUN KAN: KASNATY FẸẸ FI AṢỌ TỌRẸ F'AWỌN ALAINI KAAKIRI NAIJIRIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, March 21, 2021

AYẸYẸ ỌDUN KAN: KASNATY FẸẸ FI AṢỌ TỌRẸ F'AWỌN ALAINI KAAKIRI NAIJIRIA


Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ti ayẹyẹ ọdun kan ti gbajugbaja sọrọsọrọ agbaye nni to f'ilu Abẹokuta ṣe ibugbe, Ọgbẹni Kọlawọle Atanda Adejojo t'ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Kasnaty Sugar bẹrẹ eto oju popona, eyi to pe ni Street Voices With Kasnaty.

Ọjọ kẹrin oṣu kẹrin ọdun to kọja ni Kasnaty bẹrẹ eto ori irin naa, iyẹn lasiko konilegbele ti ajakalẹ arun korona wọ orilẹ-ede Naijiria wa. Bi ere bi awada ni Kasnaty bẹrẹ eto yii nigba naa, to si wa a di nnkan ti gbogbo agbaye n nifẹẹ si lojoojumọ titi di asiko yii.

Ki i ṣe tẹnu tabi ahesọ, awọn to ti jẹ anfaani lati ara eto yii ti le ni ẹgbẹrun meji kaakiri orilẹ-ede Naijiria lai ṣe ojusaaju ẹnikẹni.

Gbogbo awọn agbegbe ati igberiko to wa nilẹ Yoruba ni Kasnaty ti wọ lọ lati ṣe awọn eeyan lanfaani owo, dukia at'awọn nnkan mi in, koda awọn akẹkọọ naa ko gbẹyin ninu anfaani yii.

 
Laipẹ yii ni Kasnaty Sugar loun fẹẹ ṣe ayẹyẹ ọdun kan toun bẹrẹ eto naa, to si loun fẹẹ fi aṣọ tọrẹ f'awọn alaini kaakiri Naijiria, yala wọn wa sibi eto yii ni tabi wọn ko wa.

Kasnaty n'igba to n gbe ọrọ naa sọri ikanni ayelujara ti fesibuuku re, iyẹn Kasnaty Sugar, o sọ pe awọn mẹrinlelogoji loun fẹẹ fi aṣọ naa to jẹ ọpa mẹrin-mẹrin tọrẹ fun. Yatọ si eyi, o tun loun yoo fun wọn l'owo ti wọn yoo fi ran aṣọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI