FUNKẸ AKINDELE TUN RA MỌTO BỌGINNI SUV - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 17, 2021

FUNKẸ AKINDELE TUN RA MỌTO BỌGINNI SUV


Gbajugbaja òṣèré Obìnrin nni, Funkẹ Akindele Bello t'ọpọ àwọn ololufẹ rẹ mọ si Jẹnifa lo ti ra mọto bọginni ọlọyẹ olowo nla bayii, tàwọn ololufẹ rẹ káàkiri àgbáyé si n ki ku oriire. 

Ori ikanni ayélujára ti Instagraamu ni Funkẹ, iya ibeji gbe fọnran mọto naa si lati fi han awọn ololufẹ rẹ nipa òòrè tuntun ti Olodumare ṣẹṣẹ ṣe fun un.

Tuntun ni mọto yii, koda wọn ko ti i ja ọra ara rẹ lati le jẹ k'awọn eeyan mọ pe ki i ṣe tokunbọ ni mọto naa rara.

Edumare yoo dawọ le mọto naa fun un, Ọlọrun ko si ni se e ni posi fun oun pẹlu awọn ti wọn yoo jọ lo o. Amin. No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI