Owe Yorùbá kan to sọ pé 'ẹni mọ'ni lo n ṣe ni' lo lọ gẹlẹ ni ibamu pẹlú bi araadugbo kan ṣe pa ọkọ ìyàwó oju ọnà danu, to sì fi ṣe ètùtù owo l'oṣu to kọja yii.
Titi di àsìkò ta a pari ìròyìn, kayeefi nla gba a lọrọ náà ṣí n jẹ fún gbogbo àwọn tó gbọ nípa bí wọn ṣe pa gendekunrin kan ti wọn lo o jẹ ọkan lára àwọn oṣiṣẹ ijọba ti National Health Insurance Scheme (NHIS) ti fasiti awọn olukọni, ìyẹn University of Ilorin Teaching Hospital to wa nilu Ìlọrin, ipinlẹ Kwara, Olokose Oluwaṣọla Ojo danu.
Kazeem Mohammed ti wọn lo n gbe lẹgbẹ ile ti Oluwaṣọla n gbe la gbọ pé o tan Oluwaṣọla lọ sinu igbó kijikiji kan, nibi toun pẹlu awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ ibi ti pa a danu.
Gẹgẹ bí ìròyìn tó tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, wọn ni oṣù to kọja yii, ìyẹn oṣù kẹta ni Kazeem sọ fún Oluwaṣọla pe òun mọ ibi ti wọn ti n ta màlúù l'owo pọọku nilu awọn, ati pe òun yóò mú un lọ síbẹ lati ra a.
Ọjọ kẹtala oṣù kẹta náà ni wọn sọ pé Oluwaṣọla n palẹmọ lati ṣe ìgbéyàwó pẹlu ololufẹ rẹ nilu Àkúrẹ́, ipinlẹ Ondo.
Nigba to di ọjọ kẹjọ oṣù kẹta, to ku ọjọ márùn-ùn àsìkò ayẹyẹ ọjọ ìgbéyàwó náà, wọn ni Oluwaṣọla pe Kazeem lati mu oun lọ síbi tí wọn ti n pa màlúù l'owo pọọku náà.
Loju ẹsẹ níbẹ la gbọ pé Oluwaṣọla ti ko owo màlúù mẹta, ìyẹn ẹgbẹrun lọnà ọọdunrun ataabọ (N350,000) naira ti yóò fi ra a fún Kazeem.
Wọn ni aarọ ọjọ náà ni Oluwaṣọla sọ fún ololufẹ rẹ ti wọn jọ n palẹmọ ìgbéyàwó pé kò máa bọ nilu Ìlọrin lati wa a gbe màlúù ti wọn yóò pa lọ sí Àkúrẹ́.
AWIKONKO gbọ pé Kazeem ti wọn lọmọ ilu Patigi nijọba ibilẹ Kwara North ni ti gbìmọ papọ pẹlu awọn kan lati ji Oluwaṣọla gbe, ki wọn sì lè fi gba owo lọwọ àwọn èèyàn ẹ.
Oju ọnà la gbọ pé wọn wà tí wọn fi ya sinu igbó kan nilu Patigi, nibi ti wọn láwọn to n duro dè wọn wà, to sì jẹ pé loju ẹsẹ ni wọn ti jí Oluwaṣọla gbe wọnú igbó.
Lẹyìn èyí la gbọ pé wọn fi foonu Oluwaṣọla pe awọn ẹbí ẹ pé awọn ti jí í gbé, ati pe mílíọ̀nù mejila (N12m) naira láwọn yóò gba k'awọn to lè fi sílẹ lọ ṣe ìgbéyàwó tó ní lọkàn láti ṣe.
Pẹlu ẹbẹ ni wọn láwọn mọlẹbi Oluwaṣọla fi sọ pé àwọn yóò san mílíọ̀nù mẹta naira, ti wọn láwọn to jí í gbé gba lati gba owo naa.
Ko pẹ rárá tí wọn ni wọn fi lọ san idaji ninu owo naa, ìyẹn mílíọ̀nù kan ati ẹgbẹrun lọnà igba (N1.2m) naira, yatọ sí pé wọn ti gba owo tó féé fi ra màlúù mẹta lọwọ ẹ.
Wọn ni kaadi ti wọn fi n gba owo, ìyẹn ATM to jẹ ti Oluwaṣọla ni wọn lọ fi gba owo naa, koda ti wọn tun gba owo oṣù rẹ ti oṣù náà ko to di pe wọn pa a lati fi ṣe ètùtù owo.
Nigba ti wọn ni wọn kò gburo Oluwaṣọla at'awọn to jí í gbé mọ lo mu ki wọn lọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, ti wọn sì bẹrẹ iṣẹ ìwádìí loju ẹsẹ.
Kì í ṣe pé wọn deede pa Oluwaṣọla, ṣugbọn ki aṣiri ma ba a pada tu pé Kazeem lo ṣiṣẹ náà lo jẹ kí wọn pa a danu, ti wọn sì rí oku ẹ mọlẹ ninu igbó náà.
Laipẹ yii ni aṣiri pada tu pé Kazeem lo ṣiṣẹ náà, ti wọn sì láwọn ọlọpaa ti lọ gbe è lati fi oro wa a lẹnu wò.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Káyọ̀dé Ọkasanmi fi idi iṣẹlẹ naa múlẹ, o sí láwọn ti bẹrẹ sí i fi ọwọ ofin mu awọn kan, ati pe iwadii ṣí n lọ lọwọ.
No comments:
Post a Comment