O pari! Wọn ju gbajumọ Ọba Tẹjuoṣo s'atimọle ọlọpaa, awọn obinrin lo n lu ni jibiti abẹ ati owo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 24, 2021

O pari! Wọn ju gbajumọ Ọba Tẹjuoṣo s'atimọle ọlọpaa, awọn obinrin lo n lu ni jibiti abẹ ati owo


Bọsun Ọlaniyi

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, ọkan lára àwọn gbajumọ Ọba kereje n'Ipinlẹ Ogun, Ọba Adetokunbọ Tẹjuoṣo ti wa lahamọ awọn ọlọpaa.

Ẹsun agbere ati ifẹ ẹtan ori ikanni ayelujara la gbọ pé wọn fi kan Ọba Adetokunbọ Tẹjuoṣo to jẹ Olú tilu Orile Kémta n'ijọba ibilẹ Ọdẹda, ipinlẹ Ogun.

Ọkan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ lọbalọba n'ilu Ẹgba ni Ọba Adetokunbọ Tẹjuoṣo. Lára àwọn Baálẹ̀ ti ijọba Sẹnetọ Ibikunle Amosun sọ di ọba ni Ọba Tẹjuoṣo.

AWIKONKO gbọ pé àwọn kan ni wọn kọ ìwé ẹsun sí ọga ọlọpaa patapata l'orilẹ-ede yìí nípa bí Ọba Tẹjuoṣo ṣe lu wọn ni jibiti abẹ ati owo.

Gẹgẹ bá a ṣe gbọ, wọn ni ori ikanni ayelujara ti Fesibuuku ati Instagiraamu ni Ọba Tẹjuoṣo ti máa n ri awọn obinrin to máa n lu ni jibiti, pẹlu ẹtanjẹ wí pé òun yóò fi wọn  ṣe olori l'Aafin ẹ.

Wọn ni to ba ti ba wọn lo pọ tan, ṣe ni yóò já wọn ju silẹ. Koda ti wọn tun sọ pe yóò gba obitibiti owo lọwọ awọn obinrin to ba ni owo lọwọ dáadáa lẹyìn tó bá ti ba wọn laṣepọ tan.

Lara àwọn to gbe iṣẹlẹ naa ṣí wa leti sọ pé Ọba Tẹjuoṣo kì í wá awọn obinrin ti ko ba l'owo l'ọwọ kiri ori ayelujara, wọn ni obinrin to ba ti wo aworan wọn, to si ri i pé wọn l'owo lọwọ lo maa n ba sọrọ ifẹ.









No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI