Aisan Iba: Ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta ọmọde fẹẹ jẹ aafani ọfẹ nipinlẹ Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 6, 2021

Aisan Iba: Ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta ọmọde fẹẹ jẹ aafani ọfẹ nipinlẹ Kwara


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe ko din ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta awọn ọmọde kaakiri ipinlẹ naa ni yoo jẹ anfaani lati gba oogun ti yoo dena aisan iba kuro lara wọn.

Awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko ju oṣù mẹta si ọdun marun-un lọ kaakiri ijọba ibilẹ mọkanla nipinlẹ naa la gbọ pe wọn yoo jẹ anfaani yii, gẹgẹ ba a ṣe gbọ.

Oni ni awọn alakooso Ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ilera nipinlẹ naa fi ọrọ yii lede, ti wọn si ni lara owo ti Gomina AbdulRazaq bu ọwọ lu fun eto ilera awọn araalu ni wọn ti fẹẹ gbe anfaani nla naa kalẹ.

A gbọ pe awọn oogun ati irinṣẹ ti wọn yoo fi ṣiṣẹ naa ti owo rẹ ko din diẹ ni miliọnu lọna ọọdunrun ataabọ (N344m) naira ni wọn ti ri gba, ìyẹn nnu owo tijọba gbe kalẹ.

Bakan naa la tun gbọ pe ṣe lawọn oṣiṣẹ eleto ilera yoo maa lọ lati ojule kan si ekeji lati fun awọn ọmọde yii ni oogun naa lati dena aisan iba kuro lara wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI