Yunifasiti Kaduna da eto ẹkọ duro lai nidii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 8, 2021

Yunifasiti Kaduna da eto ẹkọ duro lai nidii


Awọn alaṣẹ yunifasiti t'ipinlẹ Kaduna, iyẹn Kaduna State University (KASU) lonii ti sọ pe awọn ti da gbogbo eto ẹkọ wọn to n lọwọ duro, ti wọn ko si ṣalaye nnkan to ṣẹlẹ ti wọn fi gbe igbesẹ naa.
 
Akọwe igbaniwọle yunifasiti naa, Ọgbẹni Samuel Manshop fi idi ọrọ naa mulẹ ninu atẹjade to gbe jade lonii, eyi to fi ranṣẹ sawọn akọroyin nipinlẹ Kaduna.
 
Manshop ti ko ṣalaye idi tawọn alaṣẹ naa fi gbe igbesẹ yii sọ pe eto ẹkọ yoo ṣi maa tẹsiwaju fun gbogbo awọn ti wọn ti fẹẹ pari eto ẹkọ wọn lẹka ikẹkọọ oogun medicine ati pharmacuetical scinces ati awọn to n kẹkọọ ọsan, iyẹn part-time.
 
Ọkunrin naa ninu ọrọ rẹ sọ pe "Awọn alaṣẹ KASU n fi asiko yii fi to awọn oṣiṣẹ, awọn akẹkọọ atawọn eeyan jakejado wi pe eto ẹkọ ṣi duro fun igba diẹ naa, ti a ko si ti i le sọ igba ti nnkan maa pada bọ sipo."
 
Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii fi ye wa pe awọn akẹkọọ ni wọn fẹhonu wọn han laipẹ yii lori bi awọn alaṣẹ yunifasiti naa ṣe fi kun owo ileewe ti wọn n san.
 
A gbọ pe ṣe ni wọn fi kun owo ileewe naa lati ẹgbẹrun mẹrinlelogun si mẹrindinlogoji, ti wọn si sun un soke si ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun ati ẹgbẹrun lọna irinwo naira, eyi ti wọn ni ko tẹ awọn akẹkọọ lọrun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI