Awọn ara Ọffa lawọn ṣetan lati duro ti AbdulRazaq ki ijọba rẹ le maa tẹsiwaju - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 16, 2021

Awọn ara Ọffa lawọn ṣetan lati duro ti AbdulRazaq ki ijọba rẹ le maa tẹsiwaju


Laipẹ yii ni gbogbo awọn araalu Ọffa nipinlẹ Kwara tu yaaya, ti wọn tu yaaya jade lati fi imọriri wọn han si Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori awọn ipa ribiribi to ti ko kaakiri ipinlẹ naa, paapaa ilu Ọffa laaarin ọdun meji le diẹ to de ori iṣokoso.

Wọn ni awọn iṣẹ idagbasoke ti AbdulRazaq ṣe silu Ọffa laaarin asiko to de ijọba fi han pe gomina araalu ni, ki i ṣe ẹni to wa pẹlu erongba lati kowo jẹ bi i tawọn ijọba to ti kọja lọ.

Nibi irin-ajo tawọn to di ipo oṣelu mu lati ilu Ọffa ninu iṣakoso se sawọn wọọdu kaakiri ipinlẹ naa lawọn eeyan ti sọ pe digbi lawọn wa lati maa ṣatilẹyin fun Gomina.

Awọn eeyan naa ti wọn pe ara wọn ni ‘AA Continuity Movement’, tawọn bi i Ọnọrebu Femi Agbaje Whyte, to jẹ kọmiṣanna fun ọrọ omi; Abdullahi Abdulmajeed, to jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Harmony Holdings Limited; Ọnọrebu Muhammed Kola Oyawoye; Ọnọrebu Abdulmutallib Tade Shittu; Alaaji Debo Bukoye; Alaaja Taiye Omotosho; Alaaja Aminat Gbolasere (Iya Ewe), ati Ọgbẹni Abdulwahab Kola Oluokun.

Nibẹ ni wọn ti lawọn duro digbi, ti ko si si wi pe awọn tun n boju wẹyin mọ, nitori pe ko tun sẹni to le ṣe awọn nnkan ti gomina ṣe fawọn.









No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI