Awọn aṣofin Naijiria bu ọla ikẹyin fun T.B Joshua - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 8, 2021

Awọn aṣofin Naijiria bu ọla ikẹyin fun T.B Joshua


Lonii ni gbogbo awọn aṣofin orilẹede Naijiria patapata dide iṣẹju kan lati bu ọla ikẹyin fun gbajugbaja Pasitọ nni, Temitọpe Balogun Joshua to d'oloogbe lọjọ Satide-Abamẹta to kọja yii.
 
Pasitọ T. B. Joshua ni oludasilẹ ṣọọṣi Synagogue Church Of All Nations (SCOAN) kaakiri agbaye.
 
Nibi ipade awọn aṣofin to waye lonii ti i ṣe Tusidee ni Sẹnetọ Ajayi Boroficce to n ṣoju ẹkun Ariwa ipinlẹ Ondo ti oloogbe naa ti wa fi to gbogbo ile leti wi pe Pasitọ naa ti dagbere faye.

Boroffice to jẹ igbakeji olori ọmọ ile igbimọ to pọ julọ sọ pe awọn ipa ati akitiyan ti oloogbe naa ti ko nigba to wa laye ko le parẹ titi lailai.
 
O ni oloogbe naa lo iṣẹ iranṣẹ rẹ lati ran awọn eeyan ti ko lonka lọwọ kaakiri orilẹede yii ati lagbaye.
 
Bẹẹ lo tẹsiwaju pe iranṣẹ Ọlọrun to ko gbogbo awọn ẹlẹsin miiran mọra lai fi ẹlẹyamẹya ṣe ni Wolii Joshua jẹ, eyi to loo yẹ kawọn bu ọla ati ẹyẹ ikẹyin fun un.
 
Bo ṣe pari ọrọ rẹ ni Aarẹ ile igbimọ naa, Sẹnetọ Ahmad Ibrahim Lawan sọ pe ẹdun ọkan nla lo jẹ fawọn, ati pe gbogbo awọn nnkan to n ṣẹlẹ lẹnu ọsẹ meloo kan sẹyin n fẹ idasi Ọlọrun.
 
Lẹyin eyi ni gbogbo ile dide iṣẹju kan fun Oloogbe naa, ti wọn si ni ki Ọlọrun ba wọn tẹẹ si afẹfẹ rere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI