Gomina ipinlẹ Abia, Okezie Ikpeazu ti pariwo sita wi pe kawọn eeyan ba oun wa olori ajijagbara orilẹede Biafra ti i ṣe Indigenous People of Biafra, IPOB, Mazi Nnamdi Kanu lati jokoo papọ sọrọ, to si loun ko ni ikunsinu tabi ibinu kankan si i.
Nibi ifọrọwerọ kan ti Ikpeazu ṣe pẹlu awọn akọroyin ipinlẹ naa to waye nilu Umuahia lo ti sọrọ yii, nibẹ lo si loun ti ṣetan lati jọ ba Kanu jiroro ki eto aabo le pada si bo ṣe wa tẹlẹ nipinlẹ naa atawọn agbegbe yooku ni Guusu-Ila-Oorun orilẹede yii.
O sọ pe bawọn eeyan ṣe n ba nnkan jẹ, ti wọn pawọn eeyan nipakupa kọ ni nnkan ti yoo mu ayipada ti wọn n fẹ wa, bi ko ṣe kawọn jokoo lati jiroro lori igbesẹ to kan lati ṣe.
No comments:
Post a Comment