Lai Mohammed lo maa fi ẹnu tu Naijiria ka pẹlu isọkusọ - Ọmọkri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 8, 2021

Lai Mohammed lo maa fi ẹnu tu Naijiria ka pẹlu isọkusọ - Ọmọkri


Amugbalẹgbẹ Aarẹ ana lorilẹede yii, Goodluck Jonathan, iyẹn Reno Omokri ti sọ pe bi minisita fọrọ eto iroyin ati aṣa lorilẹede yii ko ba ṣọ awọn isọkusọ to n sọ jade lẹnu, afainmọ ni ko ma jẹ pe oun ni yoo fi ẹnu rẹ tu orilẹede yii ka.

Ko si nnkan meji to mu ki Ọmọkri sọrọ yii bi ko ṣe bi Alaaji Lai Mohammed ṣe sọ pe gbogbo ẹni to ba tun lo ikanni ayelujara ti Twitter naa lẹyin aṣẹ tijọba apapọ pa lori ẹ ni wọn yoo fi oju winna ofin.
 
Awọn agbaagba ẹsin lorilẹede yii bi i Baba Adeboye ti ijọ Ridiimu; Baba Oyedepo ti ijọ Winners to fi mọ awọn mi in nidii oṣelu ni wọn ti lo ikanni ni.
 
Bawọn kan ṣe n sọ pe awọn fẹẹ wo igbesẹ ti ijọba apapọ fẹẹ gbe lori bawọn ṣe n lo ikanni naa titi di asiko yii, bẹẹ ni Lai Mohammed n sọ pe gbogbo ti aje ọrọ ba ṣi mọ lori wi pe wọn tapa si aṣẹ ijọba ipapọ yoo rija wọn laipẹ.
 
Nigba to n sọrọ, Reno Ọmọkri sọ pe Lai Mohammed ni yoo fi ẹnu rẹ tu ijọba Aarẹ Buhari ka dipo eyi tawọn ọta Buhari funra wọn n ṣe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI