Ọjọ Ibi: AbdulRazaq ba Sẹnetọ Umar yọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Tuesday, June 8, 2021

Ọjọ Ibi: AbdulRazaq ba Sẹnetọ Umar yọ


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti ba Sẹnetọ Sadiq Umar yọ fun ti ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mọkanlelaadọta to n ṣe lonii, to si gbadura ẹmi gigun ati alaafia fun un.
 
Nigba to n ṣapejuwe Sẹnetọ Umar gẹgẹ bi onirẹlẹ ati iwa tutu eeyan, AbdulRazaq sọ pe ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ APC ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin ni, to si ni awọn ipa to ti ko lawujọ ipinlẹ naa ko ṣee gbagbe.
 
O lọmọ Kwara rere tawọn yoo maa fi ojoojumọ gbe oriyin fun ni, nitori pe o ti ṣoju awọn ara agbegbe Ariwa Kwara daadaa niluu Abuja ati kaakiri agbaye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI