Ifẹsẹwọnsẹ Naijiria ati Cameroon: Rohr sọ nnkan ti yoo ṣẹlẹ lonii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Tuesday, June 8, 2021

Ifẹsẹwọnsẹ Naijiria ati Cameroon: Rohr sọ nnkan ti yoo ṣẹlẹ lonii


Akọnimọngba ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria ti awọn agbalagba, iyẹn Gernot Rohr ti sọ pe awọn bi i Ahmed Musa, Francis Uzoho ati Valentine Ozornwafor ni yoo bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ to fẹẹ waye laarin awọn ati ikọ ẹgbẹ agbabọọlu ti orilẹede Cameroon to fẹẹ waye lonii.

 
Ori ikanni Twitter ni Rohr ti fidi ọrọ yii mulẹ lanaa lẹyin ti wọn lọọ ṣe igbaradi wọn ni papa iṣere ti Wiener Neustadt.

Asiko to n dahun ibeere nipa awọn ayipada to fẹẹ waye lori ti ipalẹmọ ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu ikọ ti Indomitable Lions lati Cameroon lo sọrọ yii.

O sọ pe oun yoo gbe Musa wọle lati rọpo Kelechi Iheanacho bi wọn ba ṣe n wọle ipele ẹlẹẹkeji, nigba ti wọn yoo fi Uzoho fun Maduka Okoye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI