Ipa ti AbdulRazaq ko ni Moro laaarin ọdun meji kọja ọdun mẹrindinlogun ti PDP - Awọn alẹnulọrọ sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Tuesday, June 8, 2021

Ipa ti AbdulRazaq ko ni Moro laaarin ọdun meji kọja ọdun mẹrindinlogun ti PDP - Awọn alẹnulọrọ sọrọ


Gbogbo awọn alẹnulọrọ nijọba ibilẹ Moro, ipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn ipa ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ko laaarin ọdun meji to de ipo naa ti kọja gbogbo nnkan tawọn ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe fọdun mẹrindinlogun wọn.
 
Bode-Saadu ti wọn ti n ṣe ipade awọn agbaagba nidii oṣelu ni ọrọ yii jade laipẹ yii, ti wọn si lawọn nifẹẹ si bi Gomina AbdulRazaq ṣe sakoso ijọba rẹ lai fi ti ẹlẹyamẹya ṣe.
 
Nibi ipade naa ti wọn ti ṣe ayẹyẹ ọdun meji ti AbdulRazaq ti de ipo naa, eyi ti ẹgbẹ Moro AA Unity Forum ṣagbatẹru ẹ.

Igbakeji gomina, Ọgbẹni Kayode Alabi ti Kọmureedi Musbau Ẹṣinrogunjo ṣoju fun rọ gbogbo awọn eeyan wi pe ki wọn tubọ maa fọwọsowọpọ pẹlu Gomina naa, nitori pe awọn iṣẹ rere to ṣi fẹẹ ṣe fawọn araalu ṣi pọ rẹpẹtẹ.
 
Jagunmolu tilu Shao, Oloye Wọle Ọkẹ nigba to n sọrọ sọ pe gbogbo awọn akanṣẹ bi i opopona to ja geere, omi ẹrọ gidi, ilera pipe, ile-ẹkọ atawọn mi in ti ijọba ipinlẹ naa n ṣe ki i ṣe eyi tawọn mọ riri rẹ nikan, bi ko ṣe pe o tun fi wọn lọkan balẹ di ọjọ alẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI