Ọrọ buruku toun tẹrin-in lonii nigba ti wọn lawọn aṣoju-ṣofin orilẹ-ede yii niluu Abuja kọju ija sira wọn lori bi ijọba apapọ ṣe fofin de ikanni ayelujara ti Tuita {Twitter}.
Gbogbo awọn aṣoju-ṣofin labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP binu jade nigba ti olori ile igbimọ naa paṣẹ pe ki Ọnọrebu Kingsley Chinda to jẹ olori awọn aṣofin PDP lọọ jokoo.
Ọnọrebu Chinda la gbọ pe o n ba gbogbo ile sọrọ wi pe ki ile igbimọ naa paṣẹ lati wọgile aṣẹ ti ijọba apapọ pa lori bi wọn ṣe fofin de Tuita naa.
Wọn ni ibi to ti n sọrọ naa lọwọ ni olori ile igbimọ naa, Ọnọrebu Fẹmi Gbajabiamila ti paṣẹ wi pe ko jokoo nitori pe ko sọrọ nibẹ rara.
A gbọ pe bi Gbajabiamila ṣe sọrọ yii lawọn aṣoju-ṣofin tawọn wa lati ẹgbẹ oṣelu PDP ti bẹrẹ si i dide lati binu jade.
No comments:
Post a Comment