Ẹ wo ọmọ ọdun mẹtadinlogun to n ta igbo l'Asaba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Sunday, July 11, 2021

Ẹ wo ọmọ ọdun mẹtadinlogun to n ta igbo l'Asaba


Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Delta ti tẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan, Esealuka Paul to n ṣowo oogun oloro ati igbo niluu Asaba, ipinlẹ Delta.

Awọn ọlọpaa ti wọn pe ni Operation Delta Hawk Patrol Team ti wọn wa lori iṣẹ ayẹwo lọwọ loju ọna Cable Point lo rọwọ to Paul.
 
Ohun ta a gbọ ni pe asiko ti wọn n yẹ ara rẹ wo ni wọn ba oogun oloro ati igbo lara rẹ, ti wọn si mu lọ teṣan wọn.


Igbo ti wọn ti we sinu ọra ti ko din ni mejidinlaadọrin ni wọn ba lapo ẹ, pẹlu oogun oloro ti wọn n pe ni SK mẹtalelọgbọn, to fi mọ Razler mẹfa, pẹlu iṣana kan.
 
Ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Ari Muhammed Ali fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o si ni iwadii ti bẹrẹ lori ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI