Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara lọjọ Abamẹta, Satide ana ti ba ẹgbẹ awọn akọroyin ipinlẹ naa yọ lori bi wọn ṣe dibo yan awọn oloye tuntun fẹgbẹ na.
Ana, Satide lawọn akọroyin naa, Nigerian Union of Journalists, ẹka tipinlẹ naa ṣeto idibo, nibi ti wọn ti yan awọn ti yoo tun ṣakoso ẹgbẹ naa fọdun mẹta mi in.
Ahmed Abdullateef ti iwe iroyin Herald ni wọn dibo yan gẹgẹ bi alaga tuntun, nigba ti wọn dibo yan awọn mi in bi i igbakeji alaga, akọwe, akapo ati bẹẹbẹẹlọ.
Nigba to n sọrọ, AbdulRazaq sọ pe bi idibo naa ṣe waye bo ṣe tọ, ati bo ṣe yẹ, to si ni wọn fi iṣẹ wọn han gẹgẹ bi ẹni to n tẹle ilana ati ofin orileede yii.
No comments:
Post a Comment