TB Joṣua: Pasitọ Adeboye, Kumuyi, Oyedepo lo fa ipinya ati aiṣọkan lagboole Kristẹẹni - Wolii Ayọdele - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 11, 2021

TB Joṣua: Pasitọ Adeboye, Kumuyi, Oyedepo lo fa ipinya ati aiṣọkan lagboole Kristẹẹni - Wolii Ayọdele


Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual to wa niluu Eko, Primate Elijah Ayọdele ti sọ pe ipinya ati aiṣọkan to wa lagboole awọn ẹlẹsin Kritẹẹni ko ṣẹyin awọn agba ẹsin bi i Pasitọ Enoch Adejare Adeboye ti ijọ Ridiimu; Biṣọọbu David Oyedepo ti ijọ Winners, ati Pasitọ Williams Kumuyi ti ijọ Deeper Life.
 
Ọjọ Satide, Abamẹta ana ni Wolii Ayọdele sọrọ yii ninu ṣọọṣi ẹ, nibi ifilọlẹ iwe asọtẹlẹ ọlọdọọdun rẹ to pe ni "Warnings To The Nation", nibi to ti maa n gba awọn alaṣẹ orileede, awọn oloṣelu atawọn mi in lawujọ lamọran, ti yoo si sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ ati igbesẹ to yẹ ki wọn gbe.

O ni ikorira ati iwa ilara to wa ninu ijọ lorileede yii bẹrẹ lati ọdọ awọn agba ẹsin bi i Adeboye, Kumuyi ati Oyedepo.

Wolii Ayọdele sọrọ yii nitori bawọn agba Onigbagbọ lorileede yii ṣe kọ lati yọju sibi isinku Wolii Temitọpẹ Balogun Joshua, oludasilẹ ṣọọṣi Synagogue kaakiri agbaye, SCOAN.
 
T.B. Joṣua

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe
Bi ẹ ba n sọrọ nipa gboole Kristẹẹni, awọn eeyan maa n beere lọwọ mi pe taani mi, igba wo ni mo bẹrẹ, ati pe ẹgbẹ Onigbagbọ wo ni mo wa, ṣe PFN ni abi ewo? Emi o si nibi kankan, mi o ni baba wa ninu Oluwa, ko sẹni to kọ mi niṣẹ. Bi Ọlọrun ṣe ran mi niṣẹ ni mo ṣe n ṣe e, ti mo si da duro.
 
“Nitori naa bi ẹ ba fẹẹ sunmọ awọn eeyan kan, wọn maa sọ pe awọn ko mọ ẹ, o ko ni ipilẹ. Emi o ti i ri ibi kankan ninu bibeli ti Jesu Kristi atawọn Wolii ti lọ fun idanilẹkọọ; eyi ni ko jẹ ko ye mi bawọn kan ṣe maa n beere pe nibo leeyan duro si lagboole Onigbagbọ.
 
“Awọn agba Kristẹẹni ko fẹ kawọn ṣẹṣẹ n bọ dide, ilara ati ikorira wa lagboole Onigbagbọ, paapaa laaarin awọn olori ijọ. O si bẹrẹ lati ori Adeboye, Oyedepo, Kumuyi ati awọn mi in, awọn gan an ni wọn da wahala silẹ lagboole Onigbagbọ.
 
“Awọn olori ajọ CAN kan wa nibẹ fun apo ara wọn ni, wọn ko ṣe ohunkohun. Taani Aarẹ CAN, Oritsejiafor padanu nigba to wa nibẹ, bẹẹ naa lo ri fun Cardinal Okojie, Ayọkunle; Wọn ko ni nnkan ti wọn fẹẹ ṣe fun Igbagbọ.
 
“Ẹ lọ beere, awọn wahala ati iṣoro wa to jẹ pe wọn nilo idasi, ṣugbọn ẹ ko le ri Ayọkunle nibẹ, asiko ti wọn ba fẹẹ gba owo lẹ maa ri ko yọju. A nilo awọn to kun fun Ẹmi Mimọ ju awọn to jẹ pe owo ni wọn fi n ṣe igbagbọ wọn.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI