Lẹyn to lo ọdun meji ataabọ lẹwọn lori ẹṣẹ aimọdi, ile ẹjọ tu Thomas silẹ l'Ekiti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 4, 2021

Lẹyn to lo ọdun meji ataabọ lẹwọn lori ẹṣẹ aimọdi, ile ẹjọ tu Thomas silẹ l'Ekiti


Ile ẹjọ giga tipinlẹ Ekiti, eyi to wa nilu Ado-Eiti ti tu gendekunrin ọmọ ọdun mọkanlelogun kan, Thomas Malachy silẹ lori ẹsun aimọdi ti wọn fi kan an.
 
Diẹ lo ki ki Thomas daku ni kọọtu nigba to gbọ pe ile ẹjọ naa ti tu oun silẹ layọ ati alaafia. Bẹẹ lo tun bu sẹkun, to si n ki ara rẹ ku oriire.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla, ọdun
2018 ni wọn sọ pe Thomas lọọ jale naa lagbegbe Iworoko Ekiti, ipinlẹ naa, to si jẹ pe latigba tọwọ ti tẹ ẹ l'ọdun naa lo ti wa lahamọ awọn ọlọpaa.
 
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ John Adeyẹye sọ pe ẹsun ti wọn fi kan Thomas ko lẹsẹ nilẹ, nitori pe awọn ẹri to wa niwaju oun ko ṣee gbagbọ wi pe ọmọkunrin naa lo ṣe wọn.
 
Wọn ni ẹnikan ti wọn pe ni Kọlawọle Damilọla ni Thomas yọ ibọn si lati gba foonu,, kọmputa alagbeeka ati owo ti ko din ni ẹgbẹrun mẹtadinlọgọta lọwọ ẹ, iyẹn gẹgẹ bi agbẹjọro ọlọpaa, H.A Adeyẹmi ṣe ṣalaye fun il ẹjọ.
 
Bẹẹ ni Adeyẹmi tun sọ awọn ẹlẹri marun-un ọtọọtọ ni wọn wa jẹri si i pẹlu foonu, bata atawọn nnkan mi in lati tako Thomas.
 
Nigba toun n gba ẹnu agbẹjọro rẹ, Michael Afọlayan sọrọ, Thomas sọ pe ifurasi lasan ni wọn fura soun, ati pe oun ko mọ nnkankan nipa ẹsun ti wọn fi kan oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI