Lai Mohammed gbọdọ bẹru Ọlọrun, o si gbọdọ tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Kwara - ALGON - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 5, 2021

Lai Mohammed gbọdọ bẹru Ọlọrun, o si gbọdọ tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Kwara - ALGON


Ẹgbẹ awọn ijọba ibilẹ lorileede Naijiria, Association of Local Governments of Nigeria, (ALGON), ẹka tipinlẹ Kwara ti sọ fun minisita fọrọ aṣa ati irin ajo afẹ, Alaaji Lai Mohammed lati bẹru Ọlọrun, ati pe o ni lati tọrọ aforiji lọwọ gbogbo ọmọ ipinlẹ naa lori awọn irọ to n pa kaakiri. 
 
Ninu atẹjade ti Ọmọọba Jide Ashomibare to jẹ alaga ẹgbẹ ALGON nipinlẹ Kwara gbe jade lonii, lo ti sọ pe obitibiti miliọnu naira to wa fun ipolongo idibo ọdun 2019 nipinlẹ naa ni Alaaji Lai Mohammed gbe salọ.
 
O sọ pe oriṣiriṣi awọn eeyan, ẹlẹyinju aanu, ẹgbẹ, to fi mọ awọn alẹnulọrọ lawujọ ni wọn gbe owo kalẹ fun ipolongo idibo ọdun 2019, to si jẹ pe Alaaji Lai Mohammed ni wọn ko awọn owo naa fun, eyi to sọ pe ko fi eyikeyi ninu awọn owo naa jiṣẹ.
 
Ashomibare sọ siwaju pe o yẹ ki Lai Mohammed ko awọn owo naa kalẹ fun oludije sipo gomina nigba naa, ẹni to ti pada di gomina bayii, ṣugbọn ti ko kowo naa silẹ fẹnikẹni.
 
Bakan naa lo sọ pe iru aọn ẹsun ti wọn fi n kan ọkunrin naa ko yẹ rara, paapaa nitori ipo to di mu lorileede yii, ati pe iru ẹ ko tọ si i.
 
O ni ṣe lo yẹ ki Lai Mohammed jade sita lati ṣe akọsilẹ gbogbo awọn owo to gba, ati bo ṣe na awọn owo naa lati le wẹ ara rẹ mọ kuro ninu itiju to n ko ara rẹ si kaakiri.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI