Ayẹyẹ 'African Drum Festival' dohun igbagbe patapata nipinlẹ Ogun, wọn nijọba ti wọgi le e - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 7, 2021

Ayẹyẹ 'African Drum Festival' dohun igbagbe patapata nipinlẹ Ogun, wọn nijọba ti wọgi le e


Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
 
Ayẹyẹ aṣa ilu ilẹ adulawọ ti wọn pe ni 'AFRICAN DRUM FESTIVAL', eyi to maa n waye lọdọọdun nipinlẹ Ogun lo ti dohun igbagbe patapata bi ẹ ṣe n ka iroyin yii.
 
Ki i ṣe ahesọ tabi asọdun mọ rara wi pe ijọba ipinlẹ Ogun labẹ gomina Dapọ Abiọdun ti wọgile ayẹyẹ to n so gbogbo ilẹ adulawọ, iyẹn Afrika papọ pẹlu bi ijọba ṣe kọ lati sọ idi ti ko fi waye lati bi i oṣu mẹta sẹyin.
 
Ijọba ana nipinlẹ Ogun labẹ Sẹnetọ Ibikunle Amosun lo bẹrẹ eto naa lọdun 2016. Kọmiṣanna fun eto Aṣa, Iṣe ati Irin Ajo Afẹ nipinlẹ Ogun nigba naa, Baṣọrun Muyiwa Ọladipọ lo gbe eto naa kalẹ, ko to di pe ijọba tẹwọ gba a.

Nigba ti wọn bẹrẹ lọdun 2016, bi ere, bi awada lo ri, ṣugbọn to pada jẹ iyalẹnu nigba ti ipinlẹ ti ko din ni mọkandinlogun, ọgọta orileede lagbaye, to fi mọ orileede Afrika mẹwaa wọ ilu Abẹokuta lati ṣayẹyẹ naa. Aarin oṣu mẹrin pere ni wọn fi ṣe ipalẹmọ eto naa, to si di itẹwọgba si gbogbo aye.
 
Lọdun 2016 ti ayẹyẹ yii bẹrẹ, Nigerian Drums Festival ni wọn pe e. Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹrin, ni ayẹyẹ naa bẹrẹ, to si pari lọjọ Ẹti, Furaide, ọjọ kejilelogun, ọdun 2016.
 
Gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun, paapaa awọn ọmọ ati olugbe ilu Abẹokuta ni wọn kun fun ayọ ati imọriri lọwọ ijọba wi pe iru ayẹyẹ nla naa waye, nitori pe ṣe lo mu ki eto ọrọ aje lọ soke kọja afẹnuroyin.
 
 
Awọn ọba alade, oloye loriṣiriṣi, oṣere tiata ni wọn wa nibẹ lọjọ yii, koda, ọjọ manigbagbe ni. Bi wọn ṣe pari ayẹyẹ naa, pupọ awọn ọmọ ipinlẹ Ogun ni wọn rawọ ẹbẹ sijọba wi pe ayẹyẹ naa ko gbọdọ parun.
 

Lẹẹkan si i, ipinlẹ mọkandinlogun ni Naijiria, ọgọta orileede lagbaye, eyi ti ilẹ adulawọ mẹwaa wa lara wọn ni ilu Abẹokuta gba lalejo lọdun naa.
 
Diẹ lara awọn orileede to kopa lagbaye ni United States of America, United Kingdom, Germany, China, France atawọn mi in ti a ko le darukọ tan.
 
 
Bi ayẹyẹ yii ṣe pari, ti iroyin si kan si gbogbo agbaye, ni awọn orileede kaakiri agbaye ti bẹrẹ si i kọ lẹta ranṣẹ si ijọba ipinlẹ Ogun wi pe awọn yoo nifẹẹ lati kopa ninu ayẹyẹ naa lọdun ti yoo tẹle, iyẹn 2017.
 
Nigba ti ijọba ipinlẹ Ogun ri awọn lẹta naa gba, inu wọn dun, ori wọn wu, gẹgẹ bi a ṣe gbọ. Eyi lo jẹ ki wọn yi orukọ naa pada kuro ni Nigerian Drums Festival ti wọn fi bẹrẹ si African Drum Festival.

Ọdun 2016 ni wọn ṣiṣọ loju ilu to ga julọ nipinlẹ Ogun, nibi ti minisita fọrọ Aṣa ati Iṣe ilẹ yii, Alaaji Lai Mohammed ti dari rẹ. Iwọn bata mẹrindinlogun ni ilu ọhun, ọmọ ipinlẹ Ogun lo si ṣe ilu yii funra rẹ ni ibamu pẹlu itan.
 
Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka ko gbẹyin lọdun naa, koda, toun funra rẹ tun ṣe sadankata fun ijọba ipinlẹ naa to ṣagbatẹru ayẹyẹ naa.
 
Ko tan sibẹ, ayẹyẹ naa tun pada waye lẹẹkeji logunjọ, oṣu kẹrin, ọdun 2017, eyi gan an lo wa a fi han daju wi pe awọn eeyan nifẹẹ si aṣa ilẹ adulawọ gidi, ti wọn ko si le fi ṣere.
 

Ọdun 2017 ni ijọba ipinlẹ Ogun ṣe afihan aami idanimọ, eyi awọn oloyinbo n pe ni LOGO fun ayẹyẹ naa.
 
Idagbasoke alailẹgbẹ lo de ba ayẹyẹ naa lọdun 2019, ẹlẹẹkẹrin iru ẹ, nigba ti ipinlẹ mẹrindinlọgbọn ni Naijiria, orileede ilẹ adulawọ mẹtadinlọgbọn, awọn onilu ati agbaṣaga aladani mọkandinlaadọrin {71}, ati ọpọlọpọ orileede agbaye wọ ilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lati kopa nibi ayẹyẹ ilu ilẹ Afrika naa.
 
Gbagede Aṣa, iyẹn Amphitheater tijọba ipinlẹ Ogun n kọ lọwọ si agbegbe Oke-Ilewo kun fọnfọn, gbagede eleeyan ẹgbẹrun-un mẹwaa naa ko gba ero rara, nitori pe awọn eeyan ti kun ibẹ.

"Lilu ilu Ọjọ Iwaju", iyẹn Drumming the Future ni wọn pe akori tọdun 2019 naa.
 
Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi; Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi; Alake ilẹ Ẹgba to gbawọn ọba lalejo, Ọba Adedọtun Gbadebọ; Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka; Olu of Ilaro, Ọba Kẹhinde Olugbenle; Alaaji Lai Mohammed; Babajide Ajibọla atawọn mi in ko gbẹyin lọdun naa.
 
Gbogbo awọn Ọba ilẹ Yoruba lo sọrọ nigba naa, ti wọn si lawọn ko ti i ṣalabapade iru ayẹyẹ nla bẹẹ ri, koda ti wọn gbadura wi pe ko ni i nnkan ti yoo pana ayẹyẹ naa titi lai.
 
O ṣeni laanu wi pe  lọdun to kọja, ọdun 2020 to yẹ ki ayẹyẹ ẹlẹẹkarun-un naa waye, ajakalẹ arun korona ti wọ orileede Naijiria, to si n ba gbogbo agbaye finra.

Ijọba ipinlẹ Ogun kede sita wi pe eto ayẹyẹ naa ko ni le waye lati dẹkun itankalẹ rẹ, ati pe awọn ko ni i fẹ kawọn eeyan lagbaye tun ko arun naa wọle si i, tabi wi pe ki wọn tun ko o pada lọ si ilu wọn.

Bo tilẹ jẹ pe inu awọn eeyan ko dun si iroyin yii, paapaa awọn to ti n gbaradi, ti wọn ti n mura silẹ lati kopa, sibẹ, ko sẹni ti yoo fẹ jẹ ki arun naa kọlu oun. Idi ree ti gbogbo eeyan fi gba kamu wi pe awọn yoo mura fun ti ọdun yii.

Fawọn to ba mọ bi nnkan ṣe n lọ daadaa nipa ayẹyẹ Ọdun Ilu Ilẹ Afrika yii, ni gbogbo oṣu keji si oṣu kẹta ni awọn araalu ti maa n ni imọlara wi pe ayẹyẹ naa ti n bọ lọna, koda ti ijọba ipinlẹ Ogun funra rẹ yoo ti maa gbaradi fun ayẹyẹ yii, to si jẹ pe bi yoo ba fi ku ọsẹ kan ki ayẹyẹ naa bẹrẹ, wọn yoo pe ipade awọn akọroyin lati fi to wọn leti, ki gbogbo agbaye si le mọ bi yoo ṣe lọ si.

Iru awọn apẹẹrẹ bayii ko waye lọdun to kọja, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan mọ pe ko ni i le waye. Ṣugbọn lọdun yii, oriṣiriṣi ipejọpọ elero rẹpẹtẹ lo ti n ṣẹlẹ, ti awọn eeyan si ti n mọ iwọnba ara wọn lati dẹkun ajakalẹ arun naa nipa lilo ibomu atawọn nnkan to le dena rẹ.

Titi dasiko ta a pari akojọpọ iroyin yii, ijọba ipinlẹ Ogun ko ti i sọrọ nipa boya ayẹyẹ naa yoo waye, tabi ko ni i waye. Wọn ko ti ẹ ronu nipa rẹ rara. Bi a ba si ni ka wo o, oriṣiriṣi iroyin lo ti n jade wi pe arun korona naa ti n dohun igbagbe patapata, pẹlu bi ko ṣe si akọsilẹ awọn to n lugbadi arun naa mọ.

Ohun tawọn eeyan n sọ ni pe bi ayẹyẹ naa ko tiẹ ni waye, o yẹ ki ijọba fi to awọn araalu leti, ki wọn si sọ idi ti wọn ko fi ni i ṣe e. Kaka bẹẹ, ṣe ni ijọba panumọ, ti wọn ko si sọ ohunkohun lee lori, sibẹ awọn araalu n beere pe igba wo ni ayẹyẹ naa yoo pada ṣẹlẹ, ti eto ọrọ aje ipinlẹ Ogun yoo tun dide.

Gbogbo akitiyan wa lati ba Kọmiṣanna fọrọ Aṣa, Iṣe ati Irin-Ajo Afẹ nipinlẹ Ogun, Ọmọwe Toyin Taiwo sọrọ lati la wa lọyẹ lori idi ti ayẹyẹ naa ko ṣe waye lọdun yii lo ja si pabo. A pe e titi, ko gbe e, bẹẹ la tun fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si i, ti ko si tun da esi atẹjiṣẹ naa pada, bo tilẹ jẹ pe o ri atẹjiṣẹ wa ka.

Bakan naa ni ọkan lara awọn alẹnulọrọ ninu ijọba ipinlẹ Ogun, ẹni to tun jẹ ọkan lara awọn igbimọ eto ayẹyẹ naa, Ọnọrebu Remmy Hassan ba AWIKONKO sọrọ lori ẹ oni sọ pe oun ko le ṣalaye kulẹkulẹ nipa ẹ, ati pe ipo oun ninu igbimọ ki i ṣe agbẹnusọ.

Ọnọrebu Hassan sọ pe Kọmiṣanna fọrọ eto aṣa ati irin ajo afẹ lo lẹ ṣalaye lẹkunrẹrẹ fun wa. O tiẹ tun jẹ ka mọ pe oun yoo ba wa sọrọ nigba toun ba beere nipa idi ti ayẹyẹ naa ko fi waye lọdun yii lẹyin wakati meji si mẹta.

A ti pe aago rẹ titi, ko gbe e, titi ta a fi pari akojọpọ yii.
 
Iwoye wa ni pe, ayẹyẹ naa ti dohun igbagbe patapata pẹlu bi ijọba ko ṣe sọ nnkankan lẹyin bi oṣu mẹta sẹyin to yẹ ki ayẹyẹ naa waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI