Mọto awọn ọlọpaa gun Kẹkẹ maruwa mẹta mọlẹ, o paayan meji danu n'Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 5, 2021

Mọto awọn ọlọpaa gun Kẹkẹ maruwa mẹta mọlẹ, o paayan meji danu n'Ilọrin


Ko din ni eeyan meji ti wọn padanu ẹmi wọn laarọ kutu onii ti i ṣe ọjọ Aje, Mọnde nibi ti mọtọ awọn ọlọpaa kan ti kọlu Kẹkẹ Maruwa to n lọ jẹjẹ rẹ.
 
Ikorita agbegbe kan ti wọn n pe ni Sango, Agric to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara niṣẹlẹ ọhun ti waye, ti ọpọ awọn eeyan si farapa yannayanna. 
 
AWIKONKO gbọ pe ṣe lawọn ọlọpaa naa ti wọn n ba ere asapajude lọ pẹlu mọtọ Toyota Hilux wọn lọọ kọlu awọn Kẹkẹ Maruwa awọn n lọ jẹjẹ wọn.
 
Wọn ni ṣe ni mọto awọn ọlọpaa naa gun ori Kẹkẹ Maruwa mẹta ọtọọtọ mọlẹ, ti awọn meji si gbabẹ sọda sọrun alekeji loju ẹsẹ, tawọn mi in si farapa kọja sisọ.
 
Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu pupọ awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn. Bawọn kan ṣe n gbera ṣanlẹ sunkun, bẹẹ lawọn kan n wa ẹkun mu bi gaari Ibadan, ko to di pe awọn ẹlẹyinju aanu sare debẹ.
 
Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ fi ye wa pe iṣẹlẹ yii bi awọn ara agbegbe naa, paapaa awọn ọmọ ẹgbẹ oni Kẹkẹ Maruwa ninu, ti wọn fi bẹrẹ si i lu ọlọpaa to wa mọto naa. Koda, a gbọ pe wọn ṣaa lada, ṣugbọn ti ko ran an, ko to di pe ọlọpaa naa ba ẹsẹ rẹ sọrọ ko ma ba a ku.
  
Wọn nibi ti wọn ti n gbero lati dana mọto awọn ọlọpaa naa, ni wọn ti yiju pada si wọn, tọrọ naa si di ija igboro. Ko pẹ ni wọn lawọn ọlọpaa mi in de pẹlu tajutaju wọn, ti wọn si tun dabọn bọlẹ.

Fun bi ọpọlọpọ wakati la gbọ pe awọn ọlọpaa fi ko awọn Kẹkẹ Maruwa lagbegbe Sango-Kulẹndẹ si Maraba ti wọn ri gba lasiko iṣẹlẹ naa lọ teṣan wọn.
 
Titi dasiko ta a pari iroyin yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ko ti i sọrọ lori iṣẹlẹ yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI