Nítorí Wòlíì Ayọdele, Ààrẹ orílẹ-èdè Afríkà márùn-ùn wọ Nàìjíríà wa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, July 9, 2021

Nítorí Wòlíì Ayọdele, Ààrẹ orílẹ-èdè Afríkà márùn-ùn wọ Nàìjíríà wa


Gbogbo eto lo ti pari bayii fun gbajugbaja wolii Ọlọrun nni, Primate Elijah Ayọdele lati gba alejo awọn Aarẹ orileede ilẹ adulawọ, Afrika marun-un ọtọọtọ nibi ikojade iwe asọtẹlẹ ọlọdọọdun rẹ, eyi to jẹ ẹlẹẹkẹtadinlọgbọn iru ẹ.
 
Ọjọ Satide, Abamẹta, iyẹn ọla ode yii ni eto naa yoo waye ninu gbagede ṣọọṣi Primate Ayọdele, INRI Evangelical Spiritual Church to wa niluu Eko, nibi ti wọn yoo ti ṣe ikojade awọn iwe asọtẹlẹ to fi maa n kilọ fawọn orileede kaakiri agbaye.
 
Iwe naa to pe ni ‘Warnings To The Nations’ lo kun fun ikilọ ati asọtẹlẹ nipa awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ lọjọ iwaju, ti ẹgbẹẹgbẹrun awọn asọtẹlẹ naa si ti wa si imuṣẹ.
 
Ko si ẹka kan ti iwe yii ki i mẹnuba lọdọọdun, bo ṣe n sọrọ lori oṣelu, lo n sọrọ lori iṣẹ ati okoowo, ere idaraya, lagbo amuludun ati bẹẹbẹẹlọ. Ọdun 1994 ni wọn ti bẹrẹ si i gbe e jade.
 
Latigba ti iwe yii si ti n jade, ko din ni ẹgbẹrun mẹwaa asọtẹlẹ Wolii Ayọdele to ti wa si imuṣẹ pẹlu akọsilẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI