Nnkan de! Lai Mohammed fẹnukọ daran, lẹgbẹ oṣelu APC ba ni ko wa a kawọpọnyin rojọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, July 9, 2021

Nnkan de! Lai Mohammed fẹnukọ daran, lẹgbẹ oṣelu APC ba ni ko wa a kawọpọnyin rojọ

 
Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, afaimọ ni ko ma jẹ pe ibi ti ọrọ alaga ana fẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Kọmureedi Adams Ọṣiọmhọlẹ ja si naa ni ọrọ minisita fọrọ Aṣa ati Irin-Ajo Afẹ lorileede yii, Alaaji Lai Mohammed naa yoo pada ja si.
 
Ko si nnkan meji to fa a, bi ko ṣe ti wahala ati rogbodiyan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa nipinlẹ Kwara, eyi to jẹ pe Alaaji Lai Mohammed lo da a silẹ lati bi ọsẹ meloo kan sẹyin.

Awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC lorilẹede yii ti ranṣẹ pe Lai Mohammed lati wa a kawọpọnyin rojọ niwaju wọn lori awọn ọrọ kungbakugbe ti wọn lo n sọ si gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara.

Nibi ipade ti igbimọ oluṣakoso ipade gbogboogbo ẹgbẹ naa to fẹẹ waye, iyẹn Caretaker Extraordinary Convention Planning Committee ti Gomina Mai Mala Buni jẹ alaga rẹ ṣe laipẹ yii ni wọn ti sọ pe awọn fẹ ki Lai Mohammed wa dahun oriṣiriṣi ibeere.

Bi tilẹ jẹ pe Buni ko si nibi ipade naa, ṣugbọn awọn to wa nibẹ la gbọ pe wọn kọ iwe ranṣẹ si Mohammed lati yọju si wọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee to n bọ.

A gbọ pe inu awọn agaagba ẹgbẹ oṣelu APC ko dun rara si awọn ọrọ ti wọn ni Lai Mohammed n sọ si Gomina AbdulRazaq, paapaa bi awọn ọrọ naa tun ṣe n tu ẹgbẹ ka, eyi to mu ki wọn kọ lẹta meji ọtọọtọ ranṣẹ si baba naa.

Ninu lẹta keji la gbọ pe wọn ti fẹsun kan an wi pe agabagebe lo n ṣe ninu ẹgbẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI