Àwọn oníṣòwò ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n tún fẹ́ẹ́ jẹ anfààní owó ìṣòwò tuntun ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 31, 2021

Àwọn oníṣòwò ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n tún fẹ́ẹ́ jẹ anfààní owó ìṣòwò tuntun ni Kwara


Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn ti ṣetan lati tun jẹ kawọn oniṣowo keekeeke ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn lati jẹ anfaani owo iṣowo tuntun.
 
Oni, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ naa fidi ọrọ yii mulẹ, to si ni gbogbo awọn ọlọja ati oniṣowo keekeeke ni wọn gbọdọ jẹ mudunmudun eto oṣelu awaarawa lai ṣe ojusaaju ẹnikẹni.
 
Bẹ o ba gbagbe, lọdun to kọja ti eto yii bẹrẹ, awọn ti ko sin ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn, iyẹn 30,301 lawọn to jẹ anfaani yii ninu ipele akọkọ to bẹrẹ.
 
Lara awọn to jẹ anfaani yii ni awọn awakọ, iyẹn loṣu kẹsan, ọdun to kọja.
 
Awọn to le diẹ lẹgbẹrun mọkanla, 11,197 awakọ ni wọn kọkọ jẹ anfaani yii, ko to di pe awọn to le diẹ lẹgbẹrun mọkanlelogun, 21,623 naa tun jẹ, ti awọn ẹgbẹrun mọkandinlogun le diẹ, 19,104 diẹ naa tun jẹ.
 
Owo iṣowo tijọba ipinlẹ Kwara ṣagbatẹru rẹ yii la gbọ pe awọn oniṣowo yoo gba, ti wọn yoo si san an pada lai ni ele kankan lori.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI