O pari! Gbajumọ gomina tẹlẹri l'Ọyọ jade laye lojiji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Saturday, August 21, 2021

O pari! Gbajumọ gomina tẹlẹri l'Ọyọ jade laye lojiji


Gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ lakooko iṣẹjọba awọn ologun lorilẹ-ede yii, Jẹnẹra Adetunji Idowu Olurin ti jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọrin, 77.
 
Ilu Eko la gbọ pe Tunji Olurin ku si laaarọ oni, ọjọ Abamẹta, Satide.
 
Ọsibitu tipinlẹ Eko, iyẹn Lagos State University Teaching Hospital la gbọ pe baba naa ku si lẹni ọdun mẹtadinlọgọrin lẹyin aisan ranpẹ.
 
Aburo oloogbe, Ọgbẹni Funṣọ Olurin, lo sọ eyi di mimọ lonii, nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
 
Ọmọ bibi ilu Ilaro, nipinlẹ Ogun ni baba naa. O dije du ipo gomina ipinlẹ Ogun lọdun 2011, ṣugbọn to padanu.
 
Orẹ timọtimọ ni Olurin ati Oloye Oluṣẹgun Obasanjọ, Aarẹ tẹlẹri lorilẹ-ede yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI