Àwọn agbébọn pa ọlọ́pàá mẹ́ta danù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún dáná sun mọ́tò wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 9, 2021

Àwọn agbébọn pa ọlọ́pàá mẹ́ta danù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún dáná sun mọ́tò wọn


Ko din ni ọlọpaa mẹta ti wọn lawọn agbebọn pa danu nibi ti wọn ti n duro yẹ awọn ọkọ to n kọja lọ wo, ti wọn si tun dana sun mọto wọn ti wọn fi n ṣiṣẹ loju ẹsẹ.
 
Agbegbe kan ti wọn pe ni Obeti, eyi to wa nijọba ibilẹ Ukwuani, ipinlẹ Delta niṣẹlẹ ọhun ti waye, ti wọn si lawọn ọlọpaa mẹta lati teṣan Umutu ni wọn yinbọn pa.
 
Bo tilẹ jẹ pe AWIKONKO ko tii le fidi rẹ mulẹ boya awọn agbebọn naa ji ibọn awọn ọlọpaa yii gbe salọ lẹyin iṣẹlẹ naa, ṣugbọn ti agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ Delta, Bright Edafe fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ wi pe loootọ ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI