Nǹkan ṣe! Wọ́n ti jí àwọn òṣìṣẹ́ Ọbásanjọ́ mẹ́ta gbé l'Ógùn o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 9, 2021

Nǹkan ṣe! Wọ́n ti jí àwọn òṣìṣẹ́ Ọbásanjọ́ mẹ́ta gbé l'Ógùn o


Ko din ni awọn oṣiṣẹ aarẹ orilẹ-ede yii tẹlẹri, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti wọn lawọn ajinigbe ti jigbe salọ nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, ipinlẹ Ogun.
 
Irọle ana, Wẹside, Ọjọru la gbọ pe awọn ajinigbe naa ṣọṣẹ buruku yii ni Kọbapẹ to wa lopopona marosẹ Abẹokuta si Ṣagamu.
 
AWIKONKO gbọ pe ileeṣẹ Ọbasanjọ ti wọn pe ni Obasanjo Holdings lawọn mẹtẹẹta yii ti n ṣiṣẹ ko to di pe wọn ji wọn gbe.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ṣe lawọn ajinigbe naa tẹle mọto wọn lẹyin, ko to di pe wọn dena de wọn lojiji ni kete ti wọn de agbegbe abule Ṣẹṣẹri.

Wọn ni ṣe ni wọn dabọn bo mọto wọn lojiji, ko to di pe mọto naa duro, ti wọn si wọ awọn mẹtẹẹta wọnu igbo lọ. Alakoso eto iṣuna owo {Financial Controller}, akọwe owo {Group Auditor} ati alokoso yara ikẹrusi {Group Store Manager} lawọn mẹtẹẹta naa. 
 
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimọla Oyeyẹmi fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, to si jẹ ko ye wa pe nnkan bi aago mẹfa irọlẹ niṣẹlẹ ọhun waye.

Bẹẹ lo sọ pe iwadii ti n lọ lọwọ lori ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI