Ayé ò! Wọ́n ji olùkọ́-fẹ̀yìntì l'Ọ́ffà gbé l'Ógùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 9, 2021

Ayé ò! Wọ́n ji olùkọ́-fẹ̀yìntì l'Ọ́ffà gbé l'Ógùn


Iroyin to tẹ wa lọwọ laipẹ yii ti fi ye wa pe awọn ajinigbe tun ti ji olukọ ile-ẹkọ gbogboniṣe tilu Ọffa, iyẹn Federal Polytechnic, Ọffa, to wa nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Fasasi Ọlanigan gbe nipinlẹ Ogun.
 
Agbegbe Iṣaga to wa loju ọna Abẹokuta silu Imaṣayi la gbọ pe awọn ajinigbe naa ti dena de Ọlanigun, ti wọn si jii gbe wọnu igbo lọ.
 
A gbọ pe ṣe ni wọn fibọn da mọto ọkunrin naa duro lojiji, ko to di pe wọn digun gbe e lọ.
 
Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i gbọ boya awọn ajinigbe naa ti kan si awọn mọlẹbi Ọlanigan, yala lati gba owo ni, tabi ki wọn sọ ohun ti wọn n fẹ, sibẹ, a gbọ pe inu idaamu ati wahala lawọn mọlẹbi ọkunrin naa wa titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yii tan.

Fasasi to n gbe nilu Abẹokuta la gbọ pe wọn jigbe ni nnkan bi aago meji ọsan ana, Ọjọru, Wẹside, ti iyawo rẹ si gba teṣan ọlọpaa Lafẹnwa lọ lati lọ fi to wọn leti.

AWIKONKO gbọ pe ọrẹ Ọlaniga to wa ninu mọto Toyata Verso ti wọn gbe dani la gbọ pe o raaye na papa bora, ẹni naa lo si tu aṣiri fawọn eeyan.

Aburo Ọlanigan, Alagba Abass Ọlanigan, to jẹ oṣiṣẹ fẹyinti nipinlẹ Ogun nigba toun naa n sọrọ sọ pe ẹdun lo n jẹ fawọn wi pe wọn jigbe.
 
O ni latigba ti aburo oun ti fẹyinti ni Poli Ọffa lo ti pinnu lati ko wa sipinlẹ Ogun, nibi ti igbagbọ wa wi pe alaafia ati ifọkanbalẹ wa, lai mọ pe ohun ti yoo pada ṣẹlẹ ree.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI