Gbogbo ìgbà ni ọkọ mi máa n lù mí nítorí oúnjẹ, Màma rẹ̀ sọ pé ayé ló n ṣe é - Ìyáálé ilé ṣàlàyé fún ilé-ẹjọ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 21, 2021

Gbogbo ìgbà ni ọkọ mi máa n lù mí nítorí oúnjẹ, Màma rẹ̀ sọ pé ayé ló n ṣe é - Ìyáálé ilé ṣàlàyé fún ilé-ẹjọ́


Iyaale ile, ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Firdausi Suleiman, lọjọ Aje, Mọnde anaa lo ti bẹ ile-ẹjọ Ṣaria to wa ni  Magajin Gari, ipinlẹ Kaduna lati tu igbeyawo to wa laaarin oun ati ọkọ oun, Haruna Haruna ka ko to pẹ ju.
 
Firdausi, to n gbe lagbegbe Rigasa, lo fẹsun kan ọkọ rẹ, Haruna nibẹ pe gbogbo igba lo maa n lu oun, lati ọdun meje sẹyin tawọn ti n fẹ ara wọn, to si jẹ ko ye ile-ẹjọ pe baba oun lo fi tipatipa fẹ oun fun un nigba naa.
 
O ni ko tii si ọdun kan latigba tawọn mejeeji ti n gbe papọ, ti Haruna ko ni le oun pada sile lọdọ awọn obi oun.
 
Ninu ọrọ rẹ siwaju sii lo tun sọ pe lara awọn ẹsun ti ọkọ oun fi maa n kan oun ni pe oun jẹ ounjẹ ajẹju, to si ni gbogbo alẹ ni ọkọ oun maa n tilẹkun yara idana, nitori koun ma ba wọbẹ.
 
O jẹ ko di mimọ pe oun ti lọ fọrọ naa to mama rẹ leti, ṣugbọn to ni mama naa sọ pe aye lo n ṣe ọkọ oun, ọrọ rẹ kii ṣoju lasan, to fi n ṣe bi alaaganna.
 
O wa rawọ ẹbẹ pe ki ile-ẹjọ naa tu wọn ka, ki onikaluku si maa lọ lọtọọtọ, ati pe ki ile-ẹjọ paṣẹ lati gbe ọmọ wọn foun lati maa tọju rẹ.
 
Nigba to n tako ẹsun to fi kan an, Haruna ti agbẹjọro rẹ, M. K Mustapha ṣoju fun sọ pe ko si nnkan to jọ pe ara oun ko ya, nitori pe ori rẹ pe gidi.
 
O ni Haruna wa niluu Katsina, nibi to ti n ṣe awọn iṣẹ kọọkan.
 
Fun idi eyi, ile-ẹjọ naa ti Onidajọ Nuhu Falalu dari rẹ sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹrin, oṣu kẹwaa, to si ni kawọn mejeeji pe obi wọn dani bi wọn ba n bọ wa sile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI