Kò sí ilẹ̀ kankan tó ṣófo láti da ẹran l'Òndó - Akérédolú fi dá Miyetti Allah lójú - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, September 12, 2021

Kò sí ilẹ̀ kankan tó ṣófo láti da ẹran l'Òndó - Akérédolú fi dá Miyetti Allah lójú


Gomina ipinle Ondo ti sọ pe ko si ilẹ kankan to ṣofo, eyi to le fun awọn ọdaran, paapaa awọn Fulani darandaran lanfaani lati maa fi da maluu wọn kaakiri nipinlẹ naa.
 
Akeredolu sọ pe ipinlẹ naa ko ṣetan lati ya awọn ilẹ kan silẹ fun ẹgbẹ awọn ọdaran kankan bii ti Miyetti Allah Kataul Hore, pẹlu ẹtanjẹ lati gba alaafia ati ilọsiwaju laaye nipinlẹ naa.
 
Nigba to n gba ẹnu oludamọran pataki rẹ, Doyin Ọdẹbọwale sọrọ, Akeredolu sọ pe bi aja to n gbo mọ ẹkun lasan loun ri idunkooko ẹgbẹ Miyetti Allah naa si, ati pe ọna lati da wahala ati ogun silẹ lẹyin toun bu ọwọ lu iwe to fofin de fifofin de fifẹran jẹko kaakiri.

"Awa ko ṣetan lati fi ilẹ yoowu ninu ajogunba wa silẹ lati gba laafia ati ilọsiwaju ti awọn ẹgbẹ apaayan, ajinigbe ati afipabanilopọ lawọn fẹẹ fun wa laaye.
 
"Ko si aaye lori ilẹ wa kankan ti a le fun awọn ajoji ti wọn fẹẹ fi tipa ba wa ṣọrẹ, ti wọn si fẹẹ lo anfaani lati gba ẹtọ wa lọwọ wa."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI