Nípa ayédèrú Olúwo Ìjẹjà tí wọ́n tì mọ́lé l’Abẹ́òkúta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 11, 2021

Nípa ayédèrú Olúwo Ìjẹjà tí wọ́n tì mọ́lé l’Abẹ́òkúta


Eyi ni lati fi to gbogbo ẹyin ololufe ileeṣẹ AWIKONKO MEDIA CHANNEL to n gbe iwe iroyin AWIKONKO jade sori atẹ iwe iroyin ati lori ikanni ayelujara wi pe iroyin ti a mu wa laipẹ yii wi pe “O tan o! Mukaila, ayederu Oluwo dero atimọle l’Abẹokuta” ri bẹẹ lotitọ, ṣugbọn a n rawọ ẹbẹ wi pe a gbe aworan ‘Iwe Ileri’ ti oloyinbo n pe ni Undertaken, eyi ti Ọgbẹni Mukaila Akinwande tọwọ bọ jade sita fun gbogbo aye lati ri.

Lotitọ ni pe lọjọ kẹwaa, oṣu kẹjọ, ọdun yii, Onidajọ Ogunfowora paṣẹ pe ki Mukaila Akinwande yee pe ara rẹ ni Oluwo ilu Ijẹja mọ titi digba ti wọn yoo fi ṣe idajọ ikẹyin lori ẹjọ naa.

Lotitọ ni pe awọn ọlọpaa lati ẹkun Ibara niluu Abẹokuta lọ gbe Mukaila Akinwande nile ẹ, nitori bo ṣi ṣe n pe ara rẹ ni Oluwo ilu Ijẹja, eyi ti wọn sọ pe o tapa si aṣẹ ile ẹjọ.

Ṣugbọn sibẹ, a fẹẹ tọrọ aforijin wi pe a gbe awọn ẹri to fidi iroyin naa mulẹ sita fun gbogbo aye lati ri, nitori pe ko dun mọ Mukaila Akinwande ati gbogbo awọn ti ọrọ naa kan ninu.

Fun idi eyi, a n fi asiko yii sọ fun un yin wi pe a ti yọ gbogbo awọn aworan naa kuro lori ikanni ayelujara wa, ti a si ti fi wọn pamọ si ibi to yẹ fun akọsilẹ ọjọ iwaju.

Gẹgẹ bi ẹ ti ṣe mọ pe ‘fun igbeleke otitọ ati awijare’ ni ileeṣẹ wa duro fun, ti a ko si ni yẹgẹrẹ kuro nibẹ, a fẹẹ fi daa yin loju pe iru aṣiṣẹ bayii ko tun ni waye mọ.

Bẹẹ la tun n jẹ ko yee yin wi pe gbogbo awọn iroyin ti a ti gbe jade sẹyin lori ọrọ to nii ṣe pẹlu oye Oluwo ilu Ijẹja ṣi fẹsẹ mulẹ lai fi igba kan bo ọkan ninu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI